Kò sí ọ̀nà ti èèyàn kò lè fi pèsè ìrànlọ́wọ́ fún ará ìlú ẹ

ọkunrin kan
Àkọlé àwòrán,

Wo aláànú tó n wa ọkọ̀ tí wan fi n gbé aláìsàn lọ́fẹ̀ẹ́

Abdulkadir Abdirahman Adan ni o fi ara rẹ jin laarin agbami ado oloro ni olu ìlú Somalia.

Ọpọlọpọ ẹ̀mí ati dukia lo ti sọnu sinu ogun ti Somalia ti n ja lati ọdun to pẹ.

Kete ti Abdirahman Adan de lati orilẹ-ede Pakistan to ti lọ kọ ẹkọ iṣegun nipa itọju eyín lo ni oun ti woye pé ko si ọkọ igbe-alaisan lọ sile iwosan ni Mogadishu.

Adan ni oun woye pé ọmọlanke ni awọn eeyan ilẹ Somalia fi n gbe alaisan wọn lọ sile iwosan ni eyi ti ko boju mu rara fun ilera alaisan ni pato.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Dokita yii gbiyanju lati ran Mogadishu lọwọ

O ni perete awọn ọkọ̀ igbe-alaisan ló sile iwosan bẹẹ awọn to wa kii yọju ti ẹ ba pé wọn ati pé wọn tun n da owo gọbọi ti wọn ba jaja wa.

Àkọlé fídíò,

'Ṣíṣe àyẹ̀wò abẹ́lé fún ẹni to fẹ̀ gba gẹ́gẹ́bi òṣìsẹ́ ìnú ilé lè dóólà ẹ̀mí rẹ̀'

Ko pẹ lẹyin ti Oniṣegun oyinbo Adan de lo ronu ọna lati mu igbe aye awọn eniyan rẹ rọrun sii ni oun fi bẹrẹ iṣẹ wiwa ọkọ igboku si.

O ni oun kọkọ ra ọkọ bọọsi akero kekere, eyi ti oun tun ṣe ki o le rọrun lati fi maa gbe awọn alaisan to ba wa lori kẹkẹ nitori ailerin.

Àkọlé fídíò,

Ìwòsàn Somalia: Pàsán àti ‘Harmala’ la fi ń se ìwòsàn òògùn olóró

Lẹyin eyi lo sọọ diṣẹ iranlọwọ to fi n gbe awọn to farapa ninu ijamba ado oloro ati ninu iṣẹlẹ miran.

O tun maa n fi ọkọ rẹ gbe awọn oloyun to n rọbi lọ sile iwosan laigba kọbọ lọwọ wọn.

Àkọlé fídíò,

Somalia: 'Wọ́n pàṣẹ fún mi láti dá Ramla dúró ká tò lè ṣe igbeyàwó'

Adan bẹrẹ si ni lọ si oju ọja, gbagede èrò àti ibikibi to ba gbọ pe ijamba ti ṣẹlẹ lati maa ran wọn lọwọ ati lati beere fun iranwọ sii.

Adan salaye fun BBC pe: mo gbiyanju lati rọ awọn alaanu miran lati dide iranlọwọ paapaa awọn oniworobo ki n le rowo ra ọkọ bọọsi kekere keji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kò sí ọ̀nà ti èèyàn kò lè fi pèsè ìrànlọ́wọ́ fún ará ìlú ẹ

Adan yanana bi oun ṣe n rọ awọn akẹkọọ ti oun n kọ ni awọn ile iwe giga lati doola ẹmi awọn eniyan nipa fifi dọla kan ṣe iranwọ oṣooṣu fun ipese ọkọ gbigbe alaisan ti Aamin.

Àkọlé fídíò,

Titi Oyinsan:Tosyn Bucknor kun fun ayo, okun ati agbara

Eyi jẹ iṣẹ àkànṣe ti kò lówó ijọba ninu rara

Adan ni 'Aamin' ninu ede Somalia tumọ si 'ootọ inu' ni eyi ti ọpọlọpọ ninu awọn ara ilu gba pe oun ni Adan fi n ṣiṣẹ yii.

Bayii, adan ti gba awọn oṣiṣẹ to to marundinlogoji sẹnu iṣẹ yii ti ọpọ ninu wọn jẹ oluranlọwọ ati akẹkọọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wo aláànú tó n wa ọkọ̀ tí wan fi n gbé aláìsàn lọ́fẹ̀ẹ́

Oniṣegun oyinbo alaanu yii ni oun kii san owó oṣù fawọn oṣiṣẹ naa. funra wọn ni wọn n ṣaanu fawọn ara ilu.

Àkọlé fídíò,

Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

O ni oun maa n fun wọn ni owọ ti wọn ba na fi ra ohun eelo nigba mii ni.

Bayii, wọn ti ni ọkọ gbigbe alaisan to to ogun pẹlu awakọ fun ọkọọkan.

Dokita Adan ni awọn koi tii ri kọbọ gba lọwọ ijọba nitori awọn ti kọwe sijọba nigba kan pe ki wọn maa fi lita epo mẹwaa ran ọkọ naa lọwọ lojoojumọ ṣugbọn wọn ko tii ri esi kankan gba lati ọdọ ijọba.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ

Alaanu pọ̀ ninu eniyan ilẹ Somalia

Wiwa owo fun iranlọwọ maa n gbomi mu ṣugbọn awọn eniyan Somalia maa n ṣoore pupọ.

Dokita Adan ni oun ti ri iranlọwọ moto meji gba lati ọdọ ajọ ilera agbaye ti WHO.

Bakan naa ni wọn ti ri iranlọwọ ẹrọ ibara ẹnisọrọ lori irin gba lọwọ ajọ UNDP

O ni awọn ile iṣẹ ijoba ilẹ Gẹẹsi ni Mogadishu naa bawọn ṣeto iranlọwọ owo nipa ere idaji ni sisa.

Àkọlé fídíò,

JAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe

Iṣẹ ibi awọn alákatakítí ẹsin Isilaamu to n ju ado oloro kiri

Koko ohun to n fa wahala ni pe odiwọn nọmba to ba wu ijọba ni wọn n pe lori awọn to farapa nibi ado oloro ti awọn alakatakiti ẹsin Islam n ju ni Somalia.

Bẹẹ, awọn ile iṣẹ Aamin maa n soju abẹ niko lori odiwọn iye awọn ti wọn ba gbe lo ile iwosan fun itọju ni.

ọpọ igba ni gbọmi sii-omi-ko too ko ba ti waye laarin ijọba ati Dokita Adan ṣugbọn wọn fi suuru sii.

Ko pẹ lẹyin ti iroyin kan lọsẹ to kọja jade pe ijọba ti fofin de ile iṣẹ Aamin.

Àkọlé fídíò,

Hakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

Dokita Adan ṣalaye pe oun ti ba Kọmiṣọna ọlọpaa sọrọ lẹyin ti oun gbọ iroyin naa.

O ni kọmiṣọna ọlọpaa ti gbẹṣẹ kuro lori ofin naa pẹlu ọrọ pé a kò le sọrọ lori awọn iye eniyan to ku sinu ija naa ati awọn to farapa mọ pẹlu awọn oniroyin.

Agbẹnusọ fun ẹkun ijọba ni Somalia, Salah Hassan Omar sọ fun BBC pé aigbọraẹniye to lo ṣẹlẹ ati pe oko kan naa ni awọn mejeji jọ n ro fun idagbasoke Somalia ni.

Àkọlé fídíò,

Bí o ṣe lè fí òǹkà, ọ̀mọ̀ ìka tàbí ìkúùkù wọn oúnjẹ́

Loju Dokita Adan, awọn eniyan Somalia ṣomọluwabi pupọ. Ọrọ yii ti di ajumọṣe gbogbo ilu, funra wa ni a n mojuto nkan wa.

Awa kii ṣe ẹgbẹ oṣelu kankan

Nitootọ ni wọn ti sọ ado oloro to pọ si Mogadishu lati ọwọ awọn Al-Shabab ti wọn jẹ ọmọ ogun ọlọtẹ.

Ile iṣẹ Aamin ti ṣiṣẹ takuntakun lati pese iranlọwọ to yẹ fawọn eniyan lai naani ẹya tabi boya ọmọde tabi agba ni o nilo wọn.

Dokita Adan ni awọn ni awọn olutọju alaisan atawọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ fun ilera awọn eniyan Somalia.

O ni adura ati iwoye oun ni ọjọ iwaju rere fun Somalia ti ẹnikẹni ko ni ṣọfọ mọ lataari aisi iranlọwọ lasiko.

Àkọlé àwòrán,

Losu keji odun 2018 pelu atunse

Dokita Adan ni yoo jẹ idunnu nla fun oun ti ile iṣẹ Aamin ba n pese iranlọwọ ọkọ lasiko kaakiri gbogbo Somalia.

O ni ko si ohun ti Olorun ko lee ṣe lati gba apa kan ileto ti awọn alakatakiti ẹgbẹ Al-Shabab n dari.

Imọ pe awọn alakatakiti Islam Al-Shabab maa n beere fun owó ìtanràn ati owo ipese aabo lọwọ awọn olokowo koda ni Mogadishu ti wọn ti lé wọn ni 2011 kò dá Aamin duro.

Ni ipari, Dokita Adan sọ fun BBC pe: Awa ki ṣe ẹgbẹ oṣelu kankan, a ko da ile iṣẹ yii silẹ lati fi jèrè bẹẹ a ko mọ ohun ti ẹgbẹ́ Al-Shabab le maa wa lọwọ wa.