Kílódé tí ìjọba Nàíjíríà kò fòpin sí lílo ike rọ́bà lẹ́ẹ̀kan?

ROBA Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àjọ tó ń rísí ọ̀rọ̀ ojú ọ́jọ́ ti ní Naijiria sí ń lo ike nígbàkúgbà lẹ́ẹ̀kan sọsọ lẹ́yìn tí àwọn orílẹ̀èdè míràn ti fí òpin si.

Ajọ to n risi ọrọ oju ọjọ ti ni ọpọlọpọ ipenija lo wa ninu ki orilẹ-ede kọ lati maa lo ike nigba gbogbo lati daabo bo ayika.

Atâyi Babs to jẹ adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ti ni ida aadọrun eniyan lo n lo ike rọba lai si pe wọn maa tun un lo nigba miran lati dawọ ẹkun omi duro lagbaye.

Ninu ọrọ rẹ, Babs ni iwadii lati Ajọ Ocean Conservancy f han pe ike rọba yoo pọ ju ẹja lọ ninu okun ni ọdun 2050.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSegalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

O ni awọn n ra ike rọba miliọnu kan lagbaye ni isẹju aaya kan, ti awọn si n lo to triliọnu marun un ike rọba lọdọọdun.

Image copyright Barcroft Media
Àkọlé àwòrán Ta ike rọba ki o di olowo

Atâyi Babs fi kun un wi pe ijọba apapọ Naijiria ni isẹ pupọ lati se, lati ri i wi pe opin de ba lilo ike rọba ni awọn igberiko, ẹsẹ kuku ati awọn ilu nla nla.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lilo ike rọb lẹẹkan n ṣakoba fun ayipada oju ọjọ ni agbaye ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSegalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

Adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ni ilẹ Afirika bii Côte d'Ivoire, Cameroon, Mauritania, Tunisia, Kenya, Uganda, Rwanda, Tanzania, Morocco ati South Africa lo ti gba lati f'opin si lilo ike rọba ati ipenija rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe