US Embassy: Ìdùnnù wa kọ́ ni kí á má fún ọmọ Nàìjíríà ní 'Visa

Asia orilẹede America Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn kan gbagbọ pe orilẹ-ede America mọọmọ n fi iwe irinna dun awọn ọmọ Naijiria laini idi pataki kankan.

Ileeṣẹ aṣoju orilẹ-ede America ti sọ pe kii ṣe nkan idunnu tabi iwuri fun awọn oṣiṣẹ ileesẹ naa lati ma má fun awọn ọmọ Naijiria ni iwe irinna si America.

Ileeṣẹ America ni Naijiria fi alaye ọrọ naa sita ni oju opo Facebook rẹ sọ pe awọn awọn ibeere kan ti wọn maa n beere lọwọ awọn to ba kọwe beere fun iwe irinna silẹ America ni kii ṣaba ye awọn to kọwe naa, eyi to maa n fa ki wọn o maa ri iwe irinna wọn gba.

Ileeṣẹ naa ni ki awọn ọmọ Naijiria darapọ mọ 'Facebook Live' ni Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, laago meji ọsan lati gbọ ẹkunrẹrẹ alaye lori awọn ibeere lori 'DS 160'.

Wọn ni eyi ni yoo jẹ ki awọn eniyan le mọ bi wọn o ṣe maa dahun nigba yoowu ti wọn ba kọwe beere fun iwe irinna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionColorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!

Amọ ṣaa, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo tako alaye ti ileeṣẹ America sẹ naa.

Awọn kan gbagbọ pe wọn mọọmọ n fi iwe irinna dun awọn ọmọ Naijiria laini idi pataki kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe

Bi awọn kan ṣe n sọ pe irọ ni ileeṣẹ naa n pa, ni awọn kan si n sọ pe ki wọn o maa da owo pada fun ẹnikẹni ti ko ba ṣe aṣeyọri ninu ibeere fun iwe irinna naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSegalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ