Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́, ṣé ìwọ lè fàmì sí ọ̀rọ̀ yìí?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àmì ohùn ṣe pàtàkí nínú èdè Yoruba púpọ̀

Ede, aṣa, àti ìtàn orirun wà lára nkan to ya ogidi ọmọ Yorùbá sọtọ ni gbogbo agbaye.

Ede Yoruba dùn púpọ̀ ṣugbọn laisi àmì ohùn, o ṣeéṣe kó ma yé èèyàn dáadáa.

Ọrọ kan ṣoṣo maa n tumọ si nkan mẹrin nigba mii tabi ju bẹẹ lọ ni eyi ti ami ori wọn maa n fi iyatọ han bii ìgbà, igbà, ìgbá, àti igba.

BBC Yorùbá jade sọ fun awọn eniyan ki wọn fi ami sori ọrọ Olorun o sun.

Awọn mii gbaa paapaa awọn ọkunrin si iyalẹnu ọpọ ero nigba ti awọn miran ko gba ami ori ọrọ naa.

Ami ohun ṣe pataki pupọ ki a le maa gbọ ara wa ye.

E jẹ ki a fi ami ohun kọ awọn ọmọ wa ki ede ati aṣa Yoruba ma lè parun.

Related Topics