Notre-Dame Cathedral: ilé ìjọsin jù ara wọn lọ

Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Ilé ijọsin to kun fun itan

Ilé ijọsin aguda Notre-Dame to jona yii ti wa láti aadọta le ni ọgọrun mẹjọ ọdun sẹyin.

Lọjọ Aje ni ina deede sọ ninu ile ijọsin naa ni Paris.

Ilé ìjọsin yii kuro ni ilé lásan nitori pe nkan bii alejo miliọnu metala lo n wa wo iṣẹ aramọnda rẹ lọdọọdun lati kaakiri agbaye.

Ilé ijọsin Notre-Dame jẹ ikan lara awọn ile awo-dami-ẹnu to lokiki julọ ni Paris.

Itumọ orukọ ile ijọsin naa ni ede oyinbo ni: Our Lady. Ibẹ ni ibujoko Bishoobu agba ijọ Aguda ni Paris.

Erekuṣu Ìl-De-la Cité laarin Seine ni wọn kọ ilé ijọsin yii si lọdun 1163 lasiko Oba Louis keje niṣẹ bẹrẹ nibẹ.

Odun 1345 ni wọn pari kikọ ile ijọsin alarabara yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ina jo ilé ijọsin ti wọn kọ lọdun 1163

Arugbo ṣoge ri, akisa lo igba ri, lọdun 1790 ni wọn pa ile ijọsin yii tì lasiko ijajangbara awọn eniyan Faranse.

Iwe itan aroso: Notre-Dame of Paris ti Victor Hugo gbe jade lọdun 1831 ni o ṣi oju awọn eeyan pada sile ijọsin ti wọn ti pati naa.

Kete ti iwe yii jade, ni awọn eniyan tun ti ṣiwe iranti kan ile ijọsin naa.

Lọdun 1844 si 1864 ni wọn tun ile ijọsin yii kọ.

Jean Baptiste Antoniew Lassus ati Eugene Emmanuel Viollet-le Duc lawọn ayaworan ile ti wọn siṣẹ naa.

Wo itan awọn nkan to ti ṣẹlẹ nibẹ:

Ninu ile ijọsin Notre ni wọn ti de ade fun Oba Henry kẹfa ti England ni France.

Nibẹ naa ni wọn ti de ade fun Napoleon Bonaparte to gbiyanju lati daabo bo ile ijọsin naa lọdun 1804.

Lọdun 1909, ni Pope Pius X dá Joan ti Arc to ba awọn eniyan France jagun awọn iran Gẹẹsi fun ọpọlọpọ ọdun lọla nibẹ.

Ki lo ṣẹlẹ nigba ti ina sọ?

Lọjọọjọ Aiku ni wọn ṣi maa n ṣe isin ninu ilé ijọsin naa.

Wọn ti bẹrẹ iṣẹ atunṣẹ ni kikun sile ijọsin Notre-Dame nitori pe oorun ti jẹ ki o maa dogbo lati ọjọ pipẹ wa.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ina lagbara pupọ ko si nkan ti ko le jo

Ilé ijọsin yii ti jona ri lọdun to ti pẹ ko to tun jona ti wọn fi tun un kọ laarin ọdun 1230 si 1240.

Titi di asiko yii, wọn ko tii le sọ ohun to ṣokunfa in pato sọ lọjọ Aje yii.

Emmanuel Macro to jẹ aarẹ ile Faranse ti ṣeleri lati tun ile ijọsin naa kọ pẹlu iranlọwọ awọn eeyan.

Àkọlé àwòrán Wọn ni ọwọ awọn panapana ti ka ina naa

Lẹyin wakati mẹsan an ti ina naa ti n jo ni wọn ṣẹṣẹ n kapa ẹ.

Wọn gba pe o ṣeeṣẹ ki orisun ina naa nii ṣe pẹlu iṣẹ atunṣe nla to n lọ lọwọ.

Awọn agbofinro Paris ni iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori ohun to le fa ijamba ina naa.

Okan ninu awọn panapana to ṣiṣẹ fi ara pa ninu ijamba ina naa.

Macron ṣapejuwe iṣẹlẹ naa ni ohun to ba ni ninu jẹ pupọ.

O sọ eyi nigba ti o n ṣabẹwo sibẹ lalẹ ọjọ Aje. Aarẹ Macro ni ni wọnti ri ina naa pa ko to jo inu ile ijọsin nla gangan.

Ina naa bẹrẹ ni nkan bii ago mẹfa aabo irọle ni Paris to si ba gbogbo orule ile ijọsin naa jẹ ki ọwọ awọn panapana to kaa.

Awọn akọṣẹmọṣẹ bii Jeremy Melvin to jẹ ayaworan ile ni o to ọdun mejilelaadọsan ki wọn to kọ Notre-Dame tan tẹlẹ.

O ni eyi ri bẹẹ lataari pé imọ, ati awọn ohun eelo to wa nikawọ awọn eeyan nigba naa ko dabi ti isisnyi.