Holy Thursday: Àlúfáà àgbà ìjọ́ Anglican sọ oun tó tọ́ láti máà ṣe

Alufa agba ijọ Anglican

Oríṣun àwòrán, Olukayode Akinyemi/Facebook Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alufa agba ijọ Anglican

Ọjọ ọjọbọ mimọ, "kii ṣe ki a kan maa wẹ ẹsẹ lasan, o gbudọ ni itumọ ninu irinajo igbagbọ gẹgẹ bi ọmọlẹyin Kristi"

BBC Yoruba fọrọ wa Olukayode Akinyemi to jẹ ọkan lara awọn alufa agba ni ijọ Anglican ti orilẹede Naijiria lati fi oye ye awọn eniyan itumọ ọjọ ọjọbọ mimọ ti wọn n pe ni Holy Thursday tabi Maundy Thursday.

Ninu alaye rẹ, o ṣalaye wi pe ọjọ ọjọbọ mimọ yii ninu bibeli jẹ ọjọ irubọ Jesu Kristi lati pa ẹsẹ araye rẹ nitori oru mojumọ ọjọ yii ni ọjọ ẹti rere ti Jesu ku fun ẹsẹ araye.

Bakan naa, o ṣalaye wi pe o jẹ ọjọ ti Jesu Kristi da gbigba ara oluwa silẹ eyi ti awọn ẹlẹsin Kristẹni n pe ni isin idapọ mimọ lode oni.

Gẹgẹ bi wọn ṣe kọ ẹkunrẹrẹ rẹ ninu bibeli, iwe Johanu ori ikẹtala, alufa agba ni ọjọ yii tun jẹ iranti ọjọ ti Jesu Kristi wẹ ẹsẹ awọn ọmọ ẹhin rẹ.

Àkọlé fídíò,

Osinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"

Ninu itan yii, Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹhin rẹ pe bi oun ti o jẹ olukọ wọn ba le ṣe eyi, o yẹ ki awọn naa ṣe e fun ara wọn.

Nitori eyi ni ọpọlọpọ ijọ ṣe maa n fi eyi ṣe iranti ọjọ ọjọbọ mimọ naa. Lẹyin naa to ba di irọlẹ, wọn a pejọ si ile ijọsin lati jẹ oujẹ alẹ Oluwa eyi ti Jesu Kristi jẹ pẹlu awọn ọmọ ẹhin rẹ lọjọ naa.

Ẹwẹ, BBC bere pe ki ni ipa ti wiwẹ ẹsẹ yii nko, alufa agba Olukayode ni ipa to n ko ni ki onigbagbọ kọ iwa irẹlẹ, iwa pẹlẹ bii ti Jesu.

O ni "akókò yìí tó jẹ akoko ijiya ati iku Jesu Kristi kọ ni pe lai si ajinde Jesu kuro ninu oku, asan ni igbagbọ jẹ.