Kayode Ajulo: Ò dára kí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin buwọ́lù àwọn àbádòfin tí Buhari kọ̀sílẹ̀

Kayode Ajulo

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ọdún tó kọjá ló kọ̀ láti buwọ́lù àbádòfin lórí àtúnse ẹ̀ka tó ń sàkóso epo bẹntiról.

Ajafẹtọ ọmọniyan, Kayode Ajulo ti ni Ile Igbimọ Asofin Agba ni asẹ labẹ ofin orilẹede Naijiria lati buwọlu abadofin kan, bi aarẹ orilẹede ti lẹ kọ lati buwolu abadofin naa.

Agbẹjọro Kayọde Ajulo n fesi si igbesẹ Ile Igbimọ Asofin to buwọlu abadofin to nii ṣe pẹlu atunse ẹka epo bẹntiroo pẹlu awọn abadofin mẹfa miiran ti aarẹ kọ lati fi ọwọ si.

Àkọlé fídíò,

Osinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"

Awọn abadofin ti wọn buwọlu naa ni awọn abadofin to nii ṣe pẹlu epo bẹntiroo, ile isẹ irina lorilẹede Naijiria, ẹka iwosan, ajọ imọ sayẹnsi to n ṣe iwadii ati ajọ to n risi eto ọgbin lorilẹede Naijiria (Petroleum Industry Governance Bill, Stamp Duties Amendment Bill, National Instituete of Hospitality and Tourism Est. Bill, National Research and Innovation Council Est. Bill ati National Agricultural Seeds Council Bill).

Ajafẹtọ ọmọniyan Kayode ni igbesẹ naa dun mọ awọn ara ilu ninu ati wi pe Aarẹ Buhari naa ko binu si igbesẹ naa nitori o mọ wi pe nkan to tọna ni awọn asofin naa se.