Olubadan: ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún mi pé Ọlọwọ ti Ọwọ jade láyé

Olowo ti Owo, oloogbe Folagbade Image copyright Google/Sola Ilesanmi
Àkọlé àwòrán Olowo ti Owo, oloogbe Folagbade
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn ara ilu kede ipapodaba ọba wọn nipa gige igi nla to wa laafin.

Awọn ara ilu Ọwọ ti ge gbogbo igi nla ti won n pe ni igi ọja to wa ni aafin lati ke si awon ara ilu wi pe oba wọn ti waja ni ilu Ọwọ.

Ọlọwọ ti ilu Ọwọ waja ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹrin, ọdun 2019 ni ẹni ọdun 77.

Awọn ara ilu pe jọ si ibi ti wọn ti ilu Agogo ati ilu Oyingbo ati Ugbama Olori, lẹyin naa ni wọn ti ọja ọba pa, ti wọn si ṣi ọja lọ si ibo miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWọn ti ti ọja oba ilu naa, ti wọn si ti si ọja lọ si ibo miran.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"

Awọn lọbalọba ati awọn oloye nla nla ni ilu Ọwọ, Oloye Jamiu Ekungba ati Ọlanrewaju Famankinwa lo kede iku Ọlọwọ naa.

Awọn ọba ati ijoye ni wọn pe ọba Fọlagbade ni ẹni nla, ti o gbe igbe aye akinkanju lasiko rẹ loke eepẹ.

Bakan naa, Olubadan ti Ibadan, Oba Saliu Adetunji ti juwe Ọlọwọ ti Ọwọ gẹgẹ bi ẹni rere, to fẹran ara ilu, Ọba Saliu si tun ba awọn ara Ọwọ kẹdun ọba wọn to waja.

Related Topics