Rape Case: Tó o bá ṣàdéhùn ìfẹ́ tó ò mú u ṣẹ, ẹ̀wọ̀n lo fi ń ṣeré

Awọn ololufẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe ti ọkunrin ba kọ lati fẹ obinrin to ti ṣeleri fun pe oun yoo fi ṣ'aya, ṣe a le pe ibalopọ to ti waye laarin wọn lasiko ti wọn n rinrinajo ifẹ ni ifipanilopọ?

Ile ẹjọ to gaju l'orilẹede India sọ pe 'bẹẹni''.

Fun apẹẹrẹ, ile ẹjọ to ga julọ ni orilẹede India ti n gbẹjọ ẹsun ifipabanilopọ to ni ṣe pẹlu dokita kan ni ilu Chhattisgarh nitori pe o ni ibalopọ pẹlu ọmọbinrin kan lẹyin to ṣeleri fun pe oun yoo fi ṣ'aya, ṣugbọn to pada lọ ọ fẹ ẹlomii.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Adajọ L Nageswara Rao ati MR Shar sọ pe obinrin naa gba lati ni ibalopọ pẹlu dokita ọhun nitori pe o gbagbọ pe dokita ni erongba lati fẹ ẹ sile bi iyawo. Eyi to tumọ si pe kii ṣe pe o finu-findọ gba lati ba dokita lo pọ.

Ọrọ ibalopọ ni orilẹede India jẹ nkan to l'agbara. Niṣe ni wọn maa n diye le ìbálé ọmọbinrin. O si ṣeeṣe ko ṣoro fun obinrin to ba si ti ni ṣaaju igbeyawo lati ri ọkọ fẹ.

Awọn adajọ naa sọ pe ẹni ti wọn fi ẹsun kan ti mọ tẹlẹ pe oun ko ni i fẹ ọmọbinrin naa, pẹlu afikun pe ibalopọ to ba waye lasiko ti obinrin ṣi ọkunrin tumọ kii ṣe afinu-findọ ṣe.

Àkọlé fídíò,

Mo n wayawo - Falz ti kigbe fun awọn ololufẹ rẹ

Botilẹjẹ wi pe ile ẹjọ din ẹwọn ọdun mẹwa ti ofin la kalẹ ku si meje fun n, awọn adajọ ni 'dandan ni fun dokita naa lati jiya awọn iwa ọdaran to hu.''

Igba akọkọ kọ niyi ti iru igbẹjọ bẹ waye ni India, akọsilẹ ijọba nipa iwa ọdaran ni ọdun 2016 fihan pe ẹgbẹrun mẹwa le ni mejidinlaadọrin iru iwa ifipabanilopọ lo waye lati ọdọ ẹni ti obinrin mọ tp ṣe adehun lati fẹ ẹ sile bi iyawo.

Amọ ṣa, awọn adajọ ile ẹjọ to gaju naa damọran pe awọn ile ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun naa lati maa fi arabalẹ wo o boya lootọ ni ọkunrin fẹ fi obinrin to ba lopọ ṣ'aya tabi boya o ni erongba miran lati ibẹrẹ irinajo 'ifẹ' wọn, ṣugbọn to ṣe adehun eke ko le ba a ri ifẹkufẹ rẹ tẹlọrun.

Eyi tumọ si pe ọkunrin naa yoo le yọ ara rẹ ninu ẹsun ifipabanilopọ to ba le fidirẹmulẹ pe oun ni lọkan lati fẹ ọmọbinrin naa, sugbọn oun pada yi ero ọkan oun pada.

Ṣugbọn boṣejẹ peko rọrun lati fidi erongba ọkunrin bẹ mulẹ nile ẹjọ, a jẹ pe o ku si ọwọ adajọ to fẹ ẹ gbọ ẹsun naa lati mọ bi yoo ṣe dajọ.

Ohun kan ti awọn adajọ naa tun sọ ni pe awọn obinrin maa n lo ofin naa lati mọọmọ f'iya jẹ ọkunrin tabi gbẹsan ti irinajo ifẹ ba daru laarin a