Gani Adams: Femi Adesina, sọ fún Buhari pé ebi ń pa ọmọ Nàìjíríà

Otunba Gani Adamse Ona Kakanfo ilẹ Yoruba

Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams ta mọ olugbani nimọran pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ọrọ to kan ara ilu, Femi Adesina lori ohun to sọ pe igba Buhari dẹ awọn araalu lara.

Aarẹ Ọna Kakanfo fi ọrọ yii ran Femi Adesina si aarẹ Buhari lori ipo ti nkan wa lorilẹede Naijiria nitori latẹnu Adesina ni ọrọ aarẹ Buhari naa ti jade sita.

Àkọlé fídíò,

Ẹgbọ́n olóògbé Suga: Wọ́n yìnbọn fún Suga lójú mi, n kò sì lè dá wọn dúró

O ni "lọ sọ fun Buhari pe Naijiria n ṣẹjẹ o si gbudọ tete doju kọ awọn ohun to n damu ọpọlọpọ ọmọ Naijiria.

Ninu ọrọ̀ Adesina, o ṣe alakalẹ awọn anfani ati ayipada ti ijọba to wa lori alefa lọwọlọwọ ti ṣe lati ọdun 2015 ti wọn ti gba ijọba.

Àkọlé fídíò,

Atunto Naijiria la n fẹ - Aarẹ Onakakanfo, Gani Adams

Ṣe ni Adams fesi si Adesina pe ohun to sọ ko ri bẹẹ, o ni ipo ti orilẹede yii wa fihan gedegbe pe ọpọ ọmọ Naijiria lebi n pa ti wọn ko si nireti kankan.

Nibi eto ti wn ti pade ni ilu Eko ti ọrọ naa si jẹyọ ṣe gẹgẹ ero ọkan Gani Adams, o ni anfani nla lo jẹ fun ohun lati ba aarẹ sọrọ nipasẹ agbẹnusọ rẹ.

O ni o y ko koju mọ ṣiṣe awọn eto ti yoo ni ipa gidi ti yoo si kan aye awn eniyan to wa lẹsẹ kuku.

Oloye Gani Adams ni "arakunrin mi, ọgbẹni Femi Adeṣina ti sọ awọn ọrọ pataki nipa ipo orilẹede yii, iṣẹ rẹ ló ń ṣe. Ṣùgbọ́n mo fẹ ki o lọ sọ fun aarẹ pe Naijiria n ṣ'ẹ̀jẹ̀".

O ni pẹlu iriri oun latẹyin wa, o yẹ ki aarẹ Buhari tete da si awn ọ̀rọ̀ to ṣe gboogi to nilo akiyesi kanmọ kanmọ.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere