President George Weah: Ààrẹ fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ ní ọ́fíìsì rẹ̀ tórí ejò

Aarẹ George Weah

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ George Weah

Wọn ti ri ejo ninu ọfiisi aarẹ orilede Liberia George Weah, eyi to ti mu ko maa ṣe iṣẹ tipa tipa lati ile, BBC lo ṣe aridaju eyi.

Akọwe rẹ, Smith Toby sọ fun BBC ni ọjọru ọsẹ wi pe ṣe ni awọn ri ejo dudu meji ninu ọfiisi ẹka to n ri si ọrọ ilẹ okeere tii ṣe ibi to jẹ ọfiisi naa gangan.

Wọn ti sọ fun gbogbo oṣiṣẹ ki wọn ma lọ si inu ile naa lọ ṣe iṣẹ titi di ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin.

Ọgbni Toby sọ pe lori ki wọn kan fin ogun pako pako lo wu awọn nkan to n faya fa yii jade sita ninu ile naa.

Fidio kan to wa loju opo ile iṣẹ iroyin Front Page Africa safihan bi awọn oṣiṣẹ ṣe n gbiyanju lati pa awọn ejo naa to yri sita ni ibi igbalejo ile iṣẹ naa.

"Wọn ko tii ri awọn ejo naa pa," Ọgbẹni Toby ni oju iho kekere kan ni wọn gba sa lọ.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Eyi kii ṣe igba akọkọ nilẹ Afirika ti ẹranko ti ko yẹ ko ba ni gbe ninu ile le adari orilede sita ni ọfiisi rẹ.

Lẹyin ti wọn fin gbogbo ọfiisi aarẹ Buhari tan eleyi to na awọn ọm Naijiria to n san owo ori ni iye to to ẹgbẹrun marun abọ dollar, aarẹ Buhari kọ lati ṣiṣẹ ninu ọfiisi rẹ nitori wn ri awọn ekute nibẹ.

Ṣaaju eyi ni aarẹ Buhari rinrinajo lọ si oke okun fun eto ilera ara rẹ.

Amọ, boya wọn ri awọn ejo naa tabi wọn ko ri i, aarẹ Weah yoo pada si ọfiisi rẹ.

Awọn eniyan ri awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ ile aarẹ ti wọn duro gidigba lati ṣọ ile aarẹ eyi to wa ni olu ilu orilede naa, Monrovia.

Ọgbẹni Toby ni ile iṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni ọfiisi naa ti n fin ogun ti o lee pa ẹranko.

Àkọlé fídíò,

Osinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"