Atali Elimgbu community: Ọ̀lọ́pàá ní àbò ara ẹni ló mú ọlọ́páà pa ọdọ́ kan ní Port Harcourt

Ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, YASUYOSHI CHIBA

Àkọlé àwòrán,

Ọlọpaa Naijiria

Ohun gbogbo ko rọgbọ ni ilu Atali, ijọba ibilẹ Elimgbu ni ipinlẹ Rivers nibi ti awọn ara ilu fi ẹsun kan pe awọn ọlọpaa pa ọdọ kan ni ọjọbọ ọsẹ.

Amofin Vincent Uche to jẹ akọbi ọmọ ọba ilu naa sọ fun BBC pe wahala bẹ silẹ nigba ti ọlọpaa kan kọkọ gun ọdọ ilu kan lọbẹ pa.

O ni eyi lo mu ki awọn ọdọ to ku ya lọ si agọ ọlọpaa to wa ni ilu naa.

Kaka ki ọrọ naa ni iyanju wọn ni niṣe ni awọn ọlọpaa ṣina ibọn bo ilẹ eyi to ti mu ki ọpọ awọn ọdọ naa ba ara wọn nile iwosan.

Ninu esi ti wọn, Ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria ni lori ọrọ ẹni to ku, eyi waye lẹyin ti awọn ẹlẹgbẹ okunkun kolu awọn eniyan awọn to lọ ko wọn.

Ọlọpaa ni nigba ti wọn n lọ ọbẹ gba mọ ara wọn lọwọ ni o gun arakunrin naa nikun.

Ninu atẹjade kan ti ile iṣẹ ọlọpaa fi sita, ọga wọn patapata nibẹ, Usman Belel sọ pe nkan bii ọgọrun ọdọ lati ilu Atali lo fọ igana agọ ọlọpaa Elimgbu ti wọn si jo ile ọkan ninu awọn sagẹnti, Isreal Sunday ti wọn si ba gbogbo dukia to wa ninu rẹ jẹ.

"Awon ọdọ tun kilọ pe awọn yoo jo agọ ọlọpaa, ti kii ba ṣe ọwọ agbara ofin ti wọn lo".

Kọmisana ọlọpaa ni gbogbo ẹ ṣẹlẹ nigba ti awọn ọlọpaa to n ṣewadii iṣẹlẹ ijinigbe san ọna lọ si ilu Atali.

''Bi wọn ṣe debẹ lawọn ọdọ ilu doju kọ awọn ọlọpaa pẹlu ọbẹ. Iyẹn lo mu ki awọn ọlọpaa lọ pọ sii wa. Ọkan lara awọn ẹlẹgbẹ wa kọlu ASP Chukwuma Onuora pẹlu ọbẹ to fi di a n lọ ọ mọra ẹni lọwọ to si gun ọdọkunrin ọhun.''

"Awọn ọlọpaa gbe kẹkẹ wọ ilu Atali pe ki ọmọkunrin kan wọle. O kọ, pe ki lo de ti wọn ni ki oun wọle. Ni wọn ba jọ n fa a. Ọlọpaa kan ti wọn mọ bi ẹni n mọ owe to n jẹ Chinedu ba yọ ọbẹ fi gun ọkunrin naa".

Eyi ni alaye ti Vincent to jẹ ọmọ ilu naa ṣe lori bi o ṣe ṣẹlẹ.

O ni eyi lo mu ki awọn ọdọ ilu fariga ti wọn lọ ya bo agọ ọlọpaa Elimgbu.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

"Aafin ni awọn ọdọ wa ti ọba n ba wọn sọrọ. Ṣugbọn wọn binu gbe oku ọkunrin naa ti wọn si kọri si agọ ọlọpaa.

"Bi awọn ọlọpaa ṣe rii pe wọn n bọ ni wọn bẹrẹ si ni da ibọn bolẹ kaakiri. Wọn yin eniyan meji nibọn, lara wọn ni ọmọ ọdun mẹtala ọkunrin kan to ti n gba itọju nile iwosan bayii".

Ki ṣe igba akọkọ niyii ti ọlọpaa Naijiria yoo pa ọmọ Naijiria laipẹ yii.

Iku Kolade Johnson ni ipinlẹ Eko ati obinrin kan ni agbegbe Ajegunlẹ ni ipinlẹ kan naa ṣi wa lọkan awọn eeyan.

Ọga agba patapata awọn lọpaa si ti fa awọn ọlọpaa leti pẹlu ọpọ ofin ati ikilọ pe awọn yoo maa mu awọn ọga agọ ọlọpaa fun ipaniyan lọna aitọ.