New Minimum Wage: Òṣìṣẹ́ ń fẹ́ kí ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí san owó oṣù tuntun kíákíá

Awọn asaaju ẹgbẹ osisẹ Image copyright @NLCHQ_ABUJA

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria ti gboriyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari fun bo ṣe buwọlu sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira owo oṣu tuntun fun oṣiṣẹ.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan lati ọwọ Akọwe Apapọ fun ẹgbẹ naa, Ọmọwe Peter Ozo-Ezon.

Ṣugbọn ṣa, ẹgbẹ oṣiṣẹ n fẹ ki ofin naa di lilo ni kiakia, pẹlu alaye pe ọdun meji ni igbesẹ naa fi falẹ.

Buhari ti buwọ́lu #30,000 owó oṣù òsìsẹ́

"Gbogbo òṣìṣẹ́ kọ́ ni #30,000 owó oṣù tuntun yóò kan"

Bakan naa ni ẹgbẹ naa rọ awọn olugbanisiṣẹ, paapa ijọba apapọ ati ipinlẹ lati bẹrẹ igbesẹ to yẹ lati le sọ ọ di lilo lasiko.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin ni Aarẹ Buhari buwọlu ofin tuntun naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere