Calabar Prison: Ẹlẹ́wọ̀n bí ìbejì làǹtì lànti!

Awọn oṣiṣẹ ẹlẹwọn gbe ibeji lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, thecable.ng

Àkọlé àwòrán,

Awọn oṣiṣẹ ẹlẹwọn gbe ibeji lọ́wọ́

Ẹlẹ́wọ̀n obinrin kan ni ọgba ẹwọn Calabar, ipinlẹ Cross River ti bi ibeji lanti lanti, ọkunrin kan, obinrin kan.

Kọmisana fun eto ilera ni ipinlẹ naa, Inyang Asibong ni ọjọbọ ọsẹ ni o bi ibeji naa ninu ọgba ẹwọn ilu Calabar.

O ni kia ni awọn oṣiṣẹ oun kan sagbami iṣẹ ti wọn ti pese gbogbo iranwo ilera fun ẹlẹwọn naa.

Amọ ṣa, o ṣe ni laanu pe o ni iṣoro kan to nii ṣse pẹlu ibimọ nitori naa wọn ni lati gbe e lọ si ile iwosan akọṣẹmọṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Wo ohun tí ọkùnrin yìí ń sọ táyà ọkọ̀ dà

Ijọba ipinlẹ ti gba pe ojuṣe wọn lori awọn ọmọ wọnyii wọn si ti mu u loju paali nipa sisọ wọn lorukọ Benedict ati Linda Ayade.

O ni awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa kan sara si ijọba fun bi wọn ṣe tara ṣaṣa dahun si ipe awọn lori ipo ti ẹlẹwọn yii wa.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Nigba ti awọn oniroyin lọ si ile iwosan naa, wọn ko jẹ ki wọn ri oju iya ọlọmọ naa, wọn ni nitori o ṣi jẹ ẹlẹwọn.

Nigba ti wọn bere igba ti arabinrin naa ti wa lẹwọn, awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa ko sọ nitori wọn ni "iroyin aṣiri ni awọn ko si le fesi".