Sri Lanka Attacks: Ìbúgbàmù pa èèyàn 207 ní ilé ìjọsìn àti ilé ìtura lọ́jọ́ Àjíǹde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipaniyan nilu ṣọọṣi
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ẹbi eeyan to le lugba ti ṣagbako iṣẹlẹ ikọlu pẹlu ado oloro to waye lawọn ile ijọsin ati ile itura lọjọ Ajinde lorileede Sri Lanka.
O kere tan o to igba mẹfa ti ado oloro mẹfa dun lawọn ile ijọsin ati ile itura naa.
Aarẹ Buhari to banujẹ si iṣẹlẹ naa fero rẹ nipa oluranlọwọ rẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu.
Oríṣun àwòrán, Reuters
Ohun ta n gbọ ni pe eeyan ogun lo padanu ẹmi wọn
Aarẹ Buhari rọ awọn alaṣẹ lorilẹede Sri Lanka lati wa awọn afẹmẹṣofo to wa nidi iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi wọn jofin.
Ile ijọsin mẹta to wa ni Kochchikade, Negombo ati Batticaloa ni awọn alaburu ti yin ado oloro lasiko ijọsin Ajinde lorileede Sri Lanka.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipaniyan nilu ṣọọṣi
Iroyin ti a ri gbọ lati ọdọ ile iṣẹ iroyin AFP kọkọ sọ pe o kere tan eeyan igba lo n gba itọju lọwọ lawọn ile iwosan sugbọn o ṣeeṣe ki o ju bẹ lọ.
Ko ti daju iye eeyan to padanu ẹmi wọn ṣugbọn ikede ti a gbọ kẹyin sọ pe eeyan ọgọrun lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ko ti si ẹnikẹni to sọ pe awọn lawọn wa nidi ibugbamu naa.
Ọdun Ajinde jẹ ọkan lara awọn ọdun pataki fun awọn ẹlẹsin Kristẹni.
A ṣi n ṣe akojọpọ iroyin naa, ẹ ma tele wa kalọ lori ikanni yi fun ẹkunrẹrẹ.