Presidency: Akinkanju ológun ni Buhari, kìí ṣùn lójú ogun

Buhari

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Bishop ìpínlẹ Yola, Rev. Fr. Stephen Mamza ló fẹ̀sùn kan Ààrẹ Buhari gẹ́gẹ́ bí ológun tó ń sùn lójú ogun.

Ijọba Aarẹ Buhari ti tako ọrọ ti Bishop Ijọ Aguda Mimọ ti ilu Yola, Ẹniọwọ Fr. Stephen Mamza sọ pe aarẹ orilẹede Naijiria da bi ologun to n sun loju ogun.

Iroyin naa ni Adari ijọ naa fẹsun kan Aarẹ Buhari wi pe, ko ko ipa to jọju lati gbogun ti ẹgbẹ adunkokomọni Boko Haram.

Oludamọran pataki fun Aarẹ Buhari, Mallam Garba Shehu nigba ti o n fesi si ọrọ naa sọ wi pe, ọro to buru jai ni adari ijọ naa sọ, ati wi pe ko si otitọ nibẹ.

Àkọlé fídíò,

Irokotọla: Báwo ló ṣe rọrùn láti fi àmì sí ọ̀rọ̀ yìí, ‘Irokotọla’

Garba Shehu ni ohun gbogbo ti yi pata labẹ isakoso Aarẹ Buhari, ati wi pe awọn ti gbogun ti Boko Haram kọja ami.

Ọgọọrọ ẹmi ati dukia lo ti ba isekupani ati ado oloro ti ikọ Boko Haram fi n sekupa awọn ọmọ Naijiria lẹkun iwọ Ariwa orilẹede Naijiria.