Irú irun tí o bá n ṣe ni yóò sọ bí orí rẹ yóò ṣe rí

Ori pipa Bandile

Oríṣun àwòrán, Bandile

Àkọlé àwòrán,

Bandile ni ti oun ki i ba ṣe irun ni gbogbo igba ni, oun ko ba má pá lórí

Lasiko igba ti o yẹ ki o ma fi irun ori rẹ da ara orisirisi, n ṣe ni arabinrin yi n wa ọna lati bo asiri ori rẹ to pa.

Lati okeere, ko si apẹrẹ pe ko ni irun lori, ṣugbọn ti eeyan ba sunmọ daada, yoo ri wi pe o n koju ipenija ainirun lori.

Kii se pe o lọ sile onigbajamọ lati lọ ge irun rẹ sugbọn o seese ko jẹ pe arun kan lo fa a, ki o pa lori - irun didi lọpọ igba lo ṣakoba fun bi ori rẹ pa.

Àkọlé fídíò,

Irun gígẹ̀ kọjá orí fífá lásán

Bandile, ọmọbinrin orileede South Africa yii ni , "Nigbakugba ti mo ba ti yọ irun ti mo lẹ mọ ori mi, ṣe ni maa ni ki wọn ba mi fi ọṣẹ fọọ. Maa tun wa lẹ irun miiran mọ. Irun ti Ọlọrun fun mi ko duro lori mi ri."

Oun to n da arabinrin yii laamu ni o n jẹ 'alopecia' lede oyinbo. O ni ile iwe girama ni oun wa nigba toun ṣakiyesi wi pe irun oun n ja.

Koda, iwadii kan fi han wi pe, ọkan ninu obinrin mẹta to jẹ ọmọ adulawọ dudu, ni o n ba aisan orí pipa ja.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Irun tita jẹ owo olowo n la

Iwadii kan pẹlu ẹgbẹrun mẹfa obinrin adulawọ ni fasiti Boston ni ọdun mẹta sẹyin fi han wi pe, obinrin mejidinlaadọta ni iwaju tabi aarin ori wọn ti pa.

Amọ ọpọ igba ni awọn eniyan kii fẹ sọrọ nipa ori pipa.

Bandile ni, "Tí a ba yọ wiigi (wig) ti a wọ si ori ni ibi iṣẹ, ẹ o ri wipe, mẹjọ ninu mẹwa lori wa ti pa. A ko tilẹ maa n sọrọ nipa rẹ ni, nitori wi pe ohun itiju lo jẹ."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn obinrin adulawọ ni wọn ti gba ni imọran ki wọn mọ iru irun ti wọn yoo maa di.

Dokita kan to n gbe Ilẹ Gẹẹsi, Jumoke Koso-Thomas, ni ọṣẹ ti awọn eniyan fi n jo irun wọn lo n fa ori pipa ju, ṣugbọn ẹjẹ awọn eniyan miiran tun lee fa wahala yii.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin sọ èrò wọn lórí àríyànjiyàn ẹni tó ni ọyàn obìnrin láàrin bàbá àti ọmọ.

Dokita yii ni fun apẹẹrẹ, irun pipa le jẹyọ latara aisan òróòro.

Koso-Thomas fikun ọrọ rẹ pe ''ọmọ bibi, oogun lilo ati wahala le fa ki ori obinrin pa."

Ṣugbọn, iru ori pipa bẹẹ, fun igba diẹ ni.