Beauty tips: Ṣé ẹ gbà pé obìnrin lè kun ojú láàrín ìṣẹ́jú mẹ́ta?

Beauty tips: Ṣé ẹ gbà pé obìnrin lè kun ojú láàrín ìṣẹ́jú mẹ́ta?

Ṣíṣe ojú lóge jẹ ọkan lara ohun to ma n mu oju obinrin gun rege tabi dun un wo.

Ilana ṣiṣe oju loge gun o si fẹ plu akori nla ṣugbọn o ṣee pin si ipele ipele tabi iṣọri iṣọri.

Gẹ́gẹ́ bi awọn aṣojuloge ṣe sọ ọ, kii ṣe bi ọpọlọpọ ṣe ro o naa ni akoko ṣiṣe oju loge ṣe gun tabi kuru si, o da lori irufẹ oge oju ti o ba yan lati ṣe ati pe fun iru ode wo.

Omidan Bidemi Ajulo tẹ oju onibara rẹ kan si pẹpẹ lati ṣalaye bi obinrin to ba n lọ si ibi iṣẹ tabi ode ti ko fi bẹẹ́ gara ṣe le sare ṣe oju ara rẹ lọṣọ lai lo akoko gbọọrọ.