Lagos: Ohun mẹ́fà tó yẹ́ kí o rántí nípa Gómìnà Ambode

Gomina Ambode
Ọjọ perete lo ku fun gomina Akinwumi Ambode gẹgẹ bii gomina ipinl Eko to jẹ bii olu ilu ibudo katakara ati ọrọ aje orilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi awọn nkan to gbe ṣe yanju ṣe wa lasiko iṣejọba rẹ, bẹẹ naa ni awọn ti ko ri yanju wa.
Fun apẹẹrẹ, a o maa ṣalaye ranpẹ lori wọn labẹ akori ọrọ kọọkan.
Sunkẹrẹ Fakẹrẹ loju popo
Awọn iwe iroyin oke okun kan tilẹ jabọ iroyin pe lọdun 2012, ninu gbogbo ilu ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọ̀kọ̀ wa lagbaye, ti ilu Eko lo gbegba oroke. Gbogbo igbesẹ ati wa nkan ṣe sii kan tun bi afikun ọkọ ti awn eniyan ra ti wọn forukọ rẹ silẹ. Ijba ṣe ọna bii melo kan amọ ni ilu ti eniyan to le ni miliọnu mọkanlelogun n gbe nibẹ. Yatọ fun eyi, gẹgẹ bi ajọ ẹṣọ oju popo ṣe sọ ọ, o le ni ọkọ miliọnu meje to n gba awọn ọna Naijiria kọja eyi ti ida mẹta wọn si wa ni Eko. Oju ọna irin ko tii fi bẹẹ yanju bẹẹ si ni oju ọna omiko tii gbaju gbaja to laarin awọn eniyan ipinlẹ Eko.
Ọna/Ina ilu Eko
Lara akanṣe iṣẹ nla ti gomina Akinwumi Ambode gbe ṣe lọdun 2016 ni iṣẹ na. Ninu akanṣe iṣẹ to le lọgọrun pẹlu mẹrinla ni awọn ijọba ibilẹ ti ri ọna bii meji meji gba to si ti yanju ninu oṣu karun ọdun kan naa.
Ambode tun woye lati ri i daju pe bii adugbo to din diẹ nirinwo plu marunlelọgbọn lo ni ina ọba tori o gbagbọ pe bi ina ba wa lEko, iwa ọdaran yoo dinku.
Eto abo
Nkan bii ọkọ ogun mẹwaa ni gomina Ambode ra lẹyin oṣu melo kan to de ipo gẹgẹ bii gomina. Bakan naa ọkọ baalu fun iṣẹ ayẹwo inu ofurufu, ọkọ oju omi onibọn, ọkọ ayẹta mẹẹdogun akero atawọn ọkọ oriṣiriṣi mii fun iṣẹ abo. Pẹlu gbogbo eyi sibẹ sibẹ, ipenija ọrọ abo ṣi n yọju di diẹ.
Lake Rice
Ọkan lara awọn aṣeyọri ipinlẹ Eko lasiko pọpọṣinṣin ọdun ni ifilọọlẹ irẹsi to jẹ ajọ pese ipinlẹ Kebbi ati ipinlẹ Eko. Kẹti kẹti lawọn ara ipinlẹ Eko tu sita kaakiri ẹkun idibo mtẹta to wa lati maa ra irẹsi yii ti wọn gbe sori igba ni ẹgbẹrun mejila fun 50kg, ẹgbrun meji abọ fun 10kg. O jẹ ohun to maye dẹrun fun ọgọọrọ eeyan to n gbe ni ilu Eko paapaa lasiko ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.
Sunkẹrẹ Fakẹrẹ loju popo
Awọn iwe iroyin oke okun kan tilẹ jabọ iroyin pe lọdun 2012, ninu gbogbo ilu ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọ̀kọ̀ wa lagbaye, ti ilu Eko lo gbegba oroke. Gbogbo igbesẹ ati wa nkan ṣe sii kan tun bi afikun ọkọ ti awọn eniyan ra ti wọn forukọ rẹ silẹ. Ijba ṣe ọna bii melo kan amọ ni ilu ti eniyan to le ni miliọnu mọkanlelogun n gbe nibẹ. Yatọ fun eyi, gẹgẹ bi ajọ ẹṣọ oju popo ṣe sọ ọ, o le ni ọkọ miliọnu meje to n gba awọn ọna Naijiria kọja eyi ti ida mẹta wọn si wa ni Eko. Oju ọna irin ko tii fi bẹẹ yanju bẹẹ si ni oju ọna omiko tii gbaju gbaja to laarin awọn eniyan ipinlẹ Eko.
Ijinigbe/Ipaniyan
Pẹlu pẹlu ilọsiwaju to waye lka abo ni ipinlẹ Eko, ọdun 2016 jẹ ọdun manigbagbe nipa ijinigbe. bi wn ṣe n ji awọn ara ilu ti ko mọwọ mẹsẹ gbe ni wọn n ji awọn lọba lọba gbe. Ṣe lawọn ajinigbe n gba yiin ni ipinlẹ Eko. Ọwọ tilẹ tẹ awọn kan ti wọn si fi wọn jofin toju tiyẹ lawọn eniyan ṣi fi n ṣọ ori lai fina sori orule sun.
Bakan naa laipẹ yii, ipaniyan n peleke sii nilu Eko paapaa eyi to n waye lọna aitọ latọwọ awọn agbofinro bii ọlọpaa ati awn SARS to bẹẹ ti ọga agba awn ọlọpaa, Adamu Mohammed ṣebẹwo si ilu Eko lati fa wọn leti ati lati fi ofin ati ijiya kalẹ fun agbofinro to ba ru ofin.
Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ