Man United Vs Chelsea: De Gea d'apẹ̀rẹ̀ àjàṣẹ̀, ó fún Chelsea lẹ́bùn góòlù kan

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man United Vs Chelsea: De Gea dapẹ̀rẹ̀ àjàṣẹ̀, ó fún Chelsea lẹ́bùn góòlù kan

Òde o fi bẹ́ẹ̀ daa fún Man United lóni nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Chelsea bí asọle wọn David de Gea ṣe se àṣìṣe tó jẹ ki wọn gbá ọ̀mì pẹ̀lú Chelsea ti ó si ti depo sí ààla ireti wọn la'ti kọapa nínú Champions League ni sáà tó ń bọ ni Old Traffolrd.

Títí di àsìkò yìí Man United ti ń sàkóso ìfẹsẹwọnsẹ wọn síbẹ wọn o féèlì, wọn ò kúrò ni kílààsì, ipò kẹfà náà ni wọn si wà, sùgbọ́n wọn fi àmi àyò mẹ́tà wà lẹ́yìn Chelsea bẹ́ẹ̀ ìfẹsẹwọnsẹ mejì pere lókù fún wọn.

Bótilẹ̀ jẹ pé ọ̀mì ni wọn gbá, ó dabi pé ǹkan si sẹnure díẹ̀ fún Chelsea

Related Topics