Zainab Habib: Bí ẹ se gba Zainab sílẹ̀, ẹ gba Leah Sharibu lọ́wọ́ Boko Haram’

LEAH-ZAINAB Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Aríyànjiyàn ń lọ lórí ipa tí ìjọba kó láti gba ìtúsílẹ̀ Zainab lọ́wọ́ ìjọba Saudi nígbàtí Leah Sharibu sì wà ní pańpẹ́ Boko Haram.

Ajọ ọmọ lẹyin Kristi, CAN ti apa ariwa orilẹede Naijiria ti ba awọn obi Zainab Aliyu yọ lori pe wọn gba itusilẹ rẹ.

Ajọ CAN to bu ẹnu atẹ lu atimọle awọn ọmọ Naijiria lọna aitọ, tun ke gbajari si ijọba apapọ lati wa ọna lati gba itusilẹ Leah Sharibu to ti wa ni panpẹ ikọ Boko Haram lati Osu Keji, ọdun to kọja.

Ọpọlọpọ ariyanjiyan n lọ lori ipa ti ijọba ko lati gba itusilẹ Zainab lọwọ ijọba Saudi nigbati Sharibu ṣi wa ni panpẹ Boko Haram.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Oyin sínsìn lérè lórí ṣùgbọ́n ó tún gbé ikú karí'

Ajọ CAN naa wa ke si aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lati dari awọn eleto aabo ati ile-isẹ ologun Naijiria lati rii wi pe wọn se ohun to yẹ lati gba Leah Sharibu to jẹ ọmọ lẹyin Kristi naa silẹ.