CBN gbé ọ̀nà àbáyọ dé sí owó tó dọ̀tí

Ọgọrun naira owo Naijiria
Àkọlé àwòrán Ọgọrun naira owo Naijiria

Ile ifowopamọ to ga ju lọ lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ tuntun ti wọn yoo lo fi ko gbogbo owo idọti kuro lode.

Eyi tumọ si pe wọn yoo fi awọn owo naira tuntun rọpọ awọn to dọti gẹgẹ bi adari ẹka to ri si ẹnawo naira, arabinrin Priscilla Eleje ṣe sọ.

" Bi o ba ni awọn owo to ti ya tabi dọti, ko wọn lọ si banki, wọn yoo parọ rẹ fun ọ. Ṣugbọn bi wọn o bá gbà, fi ẹjọ wọn sun Banki to ga ju". Eyi jẹ ohun ti arabinrin Priscilla sọ.

Igbesẹ yii yoo mu ki ile ifowopamọ to ga ju lọ nitirẹ maa pese owo tuntun fun aọn banki ti yoo maa fi rọpo fun awọn eniyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Oyin sínsìn lérè lórí ṣùgbọ́n ó tún gbé ikú karí'

Agbẹnusọ fun ile ifowopamọ to ga ju lọ ni Naijiria, Isaac Okoroafor sọ pe igbesẹ tuntun yii yoo ṣeranwọ lati fopin si awọn owo ilẹ Naijiria to jẹ ayederu yoo si jẹ ki gbogbo eniyan maa na owo tuntun tuntun.

Image copyright CBN
Àkọlé àwòrán Igbesẹ owona tuntun

"Igbesẹ yii ti bẹrẹ ni ọjọ iṣẹgun, gbogbo ẹni to ba ni owo idọti lee lọ bẹrẹ si ni parọ rẹ si tuntun" Okoroafor ṣalaye.

Ẹwẹ, banki to ga ju lọ ti ni ọna ti wọn yoo gba da sẹria fun awọn banki ti ko ba gba lati parọ owo fun awọn eniyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà

Bi igbesẹ yii ṣe kan ọ

  • Yoo fun ọ ni ẹtọ lati ko owo idọti rẹ lọ si banki lati gba tuntun dipo rẹ.
  • Oo ni anfani ati pe nọmba ẹrọ ibanisọrọ kan lati fi ẹjọ banki ti ko ba gba lati parọ owo idọti rẹ fun ọ.
  • Oo ni anfani lati kọ owo idọti ti banki ba fẹ fun ọ o si le fi ẹj wọn sun ile ifowopamọ to ga ju bi wọn ba kọ lati parọ rẹ.
Image copyright CBN
Àkọlé àwòrán Igbesẹ owona tuntun
  • Igbesẹ tuntun yii n fẹ ki gbogbo eniyan maa ṣe owo ilẹ Naijiria ni pẹlẹ, ko ma dọti, ko si ma run tabi ki ẹ maa naa da silẹ.
  • Ninu igbes tuntun yii, ẹrọ ATM gan ko gbudọ maa pọ owo to dọti mọ, bi o ba wa ri pe o pọ eyi ti o dọti jade, o le fi ẹjọ rẹ sun ile ifowopamọ to ga ju lọ.