Zamfara Bandits: Kò sí ẹni tó mọ iye ènìyàn tí àwọn adigunjalè gbé lọ

Bandicts Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Zamfara Bandicts: Ko si ẹni to mọ iye ènìyàn ti àwọn adigunjale gbé lọ

Awọn afurasi adigunjale kàn ti kọlu ilé iwé Government Girls Secodary School Moriki, ni ijoba ibilẹ Zuru ipinlẹ Zamfara láárọ̀ oni, ọjọru nibi ti wọn ti da ibọn bolẹ nígbà ti wọn pa ènìyàn kan ti ko si ẹni ti o mọ iye eniyan ti gbé lọ.

Aládugbò kan ti ọ̀rọ̀ náà soju ẹ to si ba BBC sọ̀rọ̀ sàlàye pé àwọn adigunjale náà ko ni àànfani láti de ibi ti àwọn akẹkọ̀ọ́ náà sùn si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo: Mo lè jẹ Ọba ní Ile Ife

Iṣẹ̀lẹ̀ ọhun to wáye lásìkò ti àwọn ènìyàn ń wo ifẹsẹwọnsẹ to wáye láàrin Barcelona àti Liverpool.

Ipinlẹ Zamfara ti wà lábẹ ìdámu àwọn adigunjale láti ǹkan bi ọdun díẹ̀ sẹyìn, sùgbọ́n ó dàbi éni pe o ń peleke síi ni ọdun 2019 yìí.