Ajimobi ni ìlérí òun láti mú àwọn tó pa 'Ṣuga' kò yí padà

Abiola Ajimobi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Temitọpẹ Ọlatoye Ṣuga lo ṣoju fun ẹkun idibo apapọ Lagelu/Akinyele ni ipinlẹ Ọyọ ki o to ku

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iku aṣofin apapọ ipinlẹ naa kan, Temitope Olatoye ti ọpọ mọ si Ṣugar.

Ni ọjọ idibo sipo gomina ni awọn agbenipa kan yinbọn pa Ọgbẹni Temitọpẹ Akintoye.

Tani Deji Adenuga to dáná sun ènìyàn mẹ́jọ? Ọlọ́pàá ń wa

Iṣẹ́ àkànṣe tí kò parí ni Buhari ń bọ̀ wá ṣí l‘Eko - Aráàlú figbe ta

Ọwọ́ ọlọ́páá tẹ ẹyẹ ayékòótọ́ tó maa n ṣ'òfófó!

Àwòrán mánigbàgbé BBC news Yorùbá fún ọ̀sẹ̀ yìí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí ni àmì ohùn orí ''Aifagbafẹnikan'

Lasiko eto isinku rẹ to waye ni gbọngan awọn lọbalọba nilu Ibadan ni ẹgbọ aṣofin naa Ọlajide Olatoye ti paroko ikilọ ranṣẹ si gomina Ajimọbi pe ko jawọ igbesẹ to ni o n gbe lati tu awọn afunrasi ti wọn mu fun iku ẹgbọn rẹ.

O fi ẹsun kan wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n "Ṣehin-sọhun" laarin mọlẹbi oloogbe ati awọn apanilẹkun jaye.Ọlajide fi kun ọrọ rẹ wi pe ohun ti o tọ ni ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ jawọ ninu abosi, " bi wọn ko ba fẹ fi ọwọ ara wọn gbe ọmọ sin."

Amọṣa, Gomina Ajimọbi ni ko si otits ninu ọrọ naa ati pe ko si idi fun oun lati wa iku oloogbe naa tabi gbiyanju ati da apaadi bo ina eto idajọ lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to fi ran amugblẹgbẹ fun un lori eto ibanisọrọ, Bọlaji Tunji ni Gomina Ajimọbi ti ṣalaye eyi.

Ajimọbi ni ileri oun lati rii pe awọn to pa 'ṣugar' foju ba ina ofin, ileri naa ko si tii yẹ rara.

Ki o to ku, oloogbe Temitọpẹ Ọlatoye lo n ṣoju fun ẹkun idibo apapọ Lagelu/Akinyele ni ipinlẹ Ọyọ