Champions League: Ẹ ò ní dúró! Tottenham já Ajax dànù

Ajax Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wábiwọ́sí ìyà ni Ajax fi ṣe Tottenham lálejo ni Amsterdam

Agbo to tadi mẹyin , agbara lo lọ muwa lọrọ Tottenham ati Ajax ri ninu idije UEFA Champions League.

Ajax kọkọ gbo ewuro soju Tottenham nile wọn pẹlu ami ayo kan sodo ninu ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba idije Champions League.

Bakan naa ẹwẹ, Ajax lo tun kọkọ gbayo meji wọle Tottenham ninu ipele keji ere bọọlu ọhun, ko to di pe ẹlẹsẹ ayo Lucas Moura dayo meji naa pada ni kete ti abala keji bẹrẹ.

Lucas Moura, wo sunsun, lo ba tun f'ọba le pẹlu gbigba goolu kẹẹta sawọn Ajax , eyi to mu ki Tottenham pegede fun aṣekagba idije Champions League ti saa yii.

Kcee fí ọwọ́ Jóná lóri Liverpool Vs Barcelona

Sàǹgbá fọ́! Liverpool fí ogun ẹ̀yìn ja Barcelona

Ilé ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn yóò dajọ́ ìdìbò gómìnà Oṣun ọdún 2018

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajax ló kọ́kọ́ gbá góòlù méjì sáwọ̀n

Ni bayii, Tottenham ni yoo koju Liverpool ninu aṣekagba idije Champions League ti yoo waye ni papa iṣere Real Madrid ni ọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun yii