Europa League Semi-final: Chelsea rọ́ Eintracht Frankfurt lágbo dà sí iná ni Stamford Bridge

Awon agbabọọlu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Europa League Semi-final: Chelsea rọ Eintracht Frankfurt lágbo dà si iná

Chelsea gbo ewuro soju Eintracht Frankfurt pẹlu ami ayo mẹ́rin sí mẹ́ta nigba won jọ wako ni Stamford Bridge.

Awọn ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù Chelsea ń woye lati wọ asekagba, lẹ́yin ti wọn gba ọmi ayo ni ìgbà ti wọn lọ Germany, Leyin ti Luka Jovic ti peto ààye fún Frankfurt niwaju ni Pedro ba gbẹ̀yin yọ láti gba bọọlu sáwọn nibi ipele akọkọ.

Ọmi ni ayo naa gangan pari sí ki wọn to lọ abala wòmí-n-gba-sí-ọ, eyi ti Chelsea ti wa fi agba han.

Oore-ọ̀fẹ́ si wa fun Chelsea lati gba ipo kẹta.

Bóti lẹ jẹ́ pe ọmọ agbabọọlu mẹ́rin ni Chelsea ti pààrọ lẹ́yìn ìdíje wọn to wáye lopin oṣẹ́ lẹ́yìn ti wọn waàákò pẹ̀lú Watford.

Gonzalo Higuain, Pedro àti Marcos Alanzo nígbà ti N'Golo Kante fara ṣeṣe, won fi Olivier Giroud, Willian, Ruben Loftus-Cheek àti Emerson Palmeri rópò wọn, Nígbà ti Eintracht Frankfort ṣe ayipada ẹnikan pere.

Ikọ̀ Arsenal ti pegede fún aṣekagba Europa league bayìí.

Related Topics