UNICEF: O fẹ́rẹ tó 900 ọmọdé tó gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́de CJTF

Ologun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọdé tótó 894 tí gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́de tó ń kọju àwọn agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àwọn ológun.

Awọn ọmọde ẹfalelaadọruunlelẹgbẹriin (894) ti ẹrindinlaadọfa (106) lara wọn je obinrin ni wọn gba itusilẹ lọwọ awọn ọlọde to n koju awọn agbesunmọmi pelu awọn ologun(CJTF) ni Maiduguri, ariwa-oorun Naijiria loni, gẹgẹ bi ipa lati dẹkun lilo awọn ọmọde fun ikọ agbesunmọmi.

Awọn ọlọde to n koju awọn agbesunmọmi pelu awọn ologun jẹ ologun abẹlẹ to n ran awọn ọmọogun Naijiria lọwọ lati koju ikọ agbesunmọmi. Ọdun 2013 ni wọn da ikọ ologun abẹle yi silẹ lati daabo bo awọn agbegbe lọwọ ikọlu.

''Gbogbo ileri ati afojusun fun awọn ọmọde ti a ba muṣe ti a si mu lokunkundun jẹ igbesẹ ti o tọ fun aabo ẹtọ awọn ọmọde, a si ni lati satilẹ̀yin fun wọn" gẹgẹ bi Mohamed Fall, asọju ajọ UNICEF ni Naijiria ati alaga ajọ isọkan agbaye to n sabojuto ẹtọ awọn ọmọde ati ipolongo igbegidina awọn ẹtọ naa. (CTFMR).

"Awọn ọdọmọde ni Ariwa-oorun orilẹede Naijiria lo ti foriko eyi to pọju ninu rogbodiyan yii. Awọn ikọ ologun ti lo wọn fun ogun jija ati ni ona miran, eyi to ti mu wọn ri ọpọ iṣẹlẹ iku, ipaniyan ati ijamba. Ikopa ninu rogbodiyan yii ti nipa buburu fun agọ ara wọn ati ironu wọn."

Image copyright Getty Images

Lati oṣu kẹsan, ọdun 2017 ti awọn ọlọde to n koju awọn agbesunmọmi pelu awọn ologun ti jọ fọwọ siwe lati dẹkun lilo awọn ọmọde, 1,727 jẹ iye awọn ọmọde ti wọn ti tusilẹ. Lati igba naa, ko si ọmọde kankan ti awọn ọlọde to n koju awọn agbesunmọmi pelu awọn ologun tun ti gba mọra wọn mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionǸjẹ́ o mọ Yoruba daju? Fi ààmì sórí 'Bobajiroro

Awọn ọmọde ti a tu silẹ loni yoo jẹ anfani awọn eto ti yoo ṣe adapada wọn si igbe aye to boju mu, ti o si mu wọn ṣe awari ọna to tọ fun idagbasoke ati alaafia to peye wa si Naijiria gẹgẹ bii ọmọ orilẹede naa. Lai si atilẹyin yii, pupọ ninu awọn ọmọde ti a dá silẹ̀ yi ni yoo nira fun lati gbe igbe aye to boju mu, nigbati w ọn ko ni ẹkọ kankan tabi imọ iṣẹ ọwọ tẹlẹri.

Image copyright Getty Images

Ninu rogbodiyan igbesunmọmi to n lọ lọwọ ni ariwa-oorun Naijiria, o le ni 3,500 ọmọde ni wọn ti fi ipa mu lati darapọ mọ ikọ ologun abẹle laaarin ọdun 2013-2017. Ọpọ ni wọn ti jigbe, ge lapa tabi lẹsẹ, fipa ba lopọ ti awọn miran si ti ku.