Umrah 2019: Ààrẹ̀ Buhari yóò balẹ̀ bìbà sí Saudi Arabia

Aarẹ Buhari ati Ọba Saudi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ati Ọba Saudi

Aarẹ Buhari ti tẹwọ gba iwe ipeni ti Ọba Saudi Arabia, Ọba Salman Bin Abdulaziz to tun jẹ adari mọ́sálásí mimọ meji to wa fun Umrah iyẹn Hajj kekekere.

Eyi jẹ jade ninu ọrọ ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ, Garba Shehu fi sita eyi to sọ ọjọ́ ti aarẹ yoo lọ ati ọjọ ti yoo pada sile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionZainab Aliyu: Mo sọkún títí, ojé tán lóju mi ni àhámọ Saudi

Aarẹ pẹlu awọn oluranlọwọ pataki to jẹ tirẹ ni wọn yoo jọ kọwọ rin lọ ni ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun.

Ireti ni pe aarẹ aarẹ yoo pada de si orilẹede Naijiria ni ọjọ kọkanlelogun oṣu karun yii kan naa.

Umrah kii ṣe irinajo ọ̀ranyàn fun awọn musulumi ṣugbọn eyi ti wọn maa n gba wọ́n niyanju gẹgẹ bi irinajo Hajj lọ si Mekahh ti wọn lee lọ nigbakuugba to ba wu wọn ninu ọdun.