Drivers lincense renewal: Ẹgbẹ̀lẹ́gẹ̀ àwakọ ló ń lo iwé ìrinà ọ̀kọ̀ tí kò koju oṣùwọn- FRSC

Awon moto nibudoko ni Eko Image copyright Pius Utomi Ekpei
Àkọlé àwòrán Operation show your drivers license: Ẹgbẹ̀lẹ́gẹ̀ àwakọ ló ń lo iwé ìrinà ọ̀kọ̀ tí kò koju oṣùwọn- FRSC

Àjọ ẹsọ ojú pópó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (FRSC), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Eko sọ pé ẹgbẹgbẹrún ọ̀pọ̀ àwọn awakọ ní ìpínlẹ̀ Eko kò lo ojúlówó ìwé àṣẹ ìrina awakọ, yálà iwe ti wọn gbà lásiko ti wọn kọ ẹkọ́ móto tan lo wà lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn awakọ.

Ọ̀gá àgbà fún àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Eko Hyginus Omeje sọ fún BBC pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ètò ààbò tuntun, ti wọn pè ni operation "Show your Driver's license" ní ìpínlẹ̀ Eko ti yóò sì bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ ajé to n bọ, ogúnjọ́ oṣù kaarun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFRSC o gbọdọ ni ju 500 naira lọwọ

" Ìfojúsù wà ni pe kí àwọn àwakọ̀ to kójú òsùwọn máà wakọ̀ ní àwọn ojú pópó wa pẹ̀lú ìwé ìrìnà to jẹ ojúlówo ni ipinlẹ̀ Eko."

Ọ̀gá Omeje sàlàyé pé ọ̀pọ̀ ló ń wá si ilé iṣẹ́ àwọn láti wá fi orúkọ sílẹ̀ láti gba ìwé ìrìnà, sùgbọ́n ní kété ti wọn ba ti gba iwé ti yóò fi han pé wọn ti ń ṣe iwé ìrìnà wọn lọ́wọ́ ni wọn kìí pada wá mọ láti wá gba ojúlówó iwé ìrìnà wọn.

''Iwé ìrìnà ọkọ̀ tó lé ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta ló wà ni ilé iṣẹ́ wá ti kò si ẹni to bèrè fún. Iwe fidihẹ ti wọn ti gba láti ìbẹ̀rl náà ni w\]on si fi ń lóju pópó ti wọn bá dá wọn dúró láti bèrè ìwé ìrìnà wọn, kódà kii àsìkò lílò ìwé náà ti kọjá, Awọn ǹkan ti àn gbìyànjú láti fi òpín sí rèé"

" Tí a bá gbá ọkọ̀ rẹ̀ mú tí ó si le fi ìwé ìrìnà ojúlówó rẹ hàn wá, láárìn wákàti mẹ́rìnlélógun, ó san owó ìtànran, lẹ̀yìn owó ìtanràn òó si tún lọ gba ìwé ìrùnà náà kí ó to gbé mótò rẹ̀ ni àgọ wá,'' Eyí jẹ ọ̀rọ̀ Omeje

O ní kò tọ̀nà láti má ṣe àfihan ẹ̀dà ìwé ìrina ọkọ̀ kò ba ofin mu, ojulówó ni ǹkan ti àjọ FRSC ń bèrè.

Ipinlẹ Eko ni Gbọ̀gan olúlu ètò ọ̀rọ̀ ajé tí o si ní ìgbòkegbodo ọkọ̀ to pọ̀ju lọ ní orílẹ̀-èdè Naijiria

Related Topics