Arap Moi: Ilé ẹjọ́ ní kí aààrẹ Kenya àná san owó ìtanràn $10m fún opó nítorí ilẹ̀

Daniel Arap Moi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Daniel arap Moi jẹ́ aarẹ Kenya fún ọdun mẹ́rinlelogun

Bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan lotitọ yoo ba ni ọrọ Aarẹ orilẹede Kenyan nigba kan ri Arap Moi ti ile ẹjọ kan ni orilẹede naa ni ko say miliọnu mẹwa ati aabọ dọla gẹgẹ bi owo itanran fun opo kan ti o gba ilẹ rẹ ni ọdun mẹrindinlogoji sẹyin.

Moi gba ilẹ naa to le ni aadọta ékà to jẹ ilẹ opo naa Susan Cheburet Chelugui, gẹgẹ bi adajọ ṣe sọ.

Ọkọ arabinrin naa to ti di oloogbe Noah Chelugui jẹ oloye kan ni agbegbe rẹ nigba ti Moi jẹ aarẹ.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ọmọ oloogbe naa David Chelugui fi ẹsun kan aarẹ ana naa wipe o gba ilẹ idile wọn lẹyin ti baba oun ku.

Lẹyin to gba ilẹ naa, Moi ta ilẹ naa fun ileeṣẹ Rai Plywood kan to n ta igi gẹdu.

Ileeṣẹ naa sọ fun ile ẹjọ wipe ọdun 2007 ni Moi ta ilẹ naa fun awọn.

Adajọ Anthony Ombwayo ni Moi ko mu ẹri kankan wa to fi han bi o ṣe ni onilẹ naa.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí