Samuel Okwaraji: Ká ní kò dágbére fáyé ni, òní ni Samuel Okwaraji kò bá pé ọmọ ọdún 55

Sam Okwaraji Image copyright Nairaland
Àkọlé àwòrán Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 1964 ni wọn bi agbabọọlu naa

Odu agbabọọlu orilẹede Naijiria ni Samuel Sochukwuma Okwaraji jẹ ni igba aye rẹ, o si ṣoju orilẹede Naijiria fun ọpọ ifẹsẹwọnsẹ. Agbẹjọro to kawe gboye ni o si tun ni iwe ẹri imọ ijinlẹ keji ninu imọ ofin ajọṣepọ ilẹ okeeere, (Masters in International Law)

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 1964, ni wọn bi Sam Okwaraji ni ilu Orlu ni ipinlẹ Imo, o si gba bọọlu jẹun lawọn ẹgbẹ agbabọọẹu to lorukọ ni ilẹ Yuroopu bi AS Roma (1984-1985), NK Dinamo Zagreb (1985-1986), Austria Klagenfurt (1986-1987), VfB Stuttgart (1987-1989) ati SSV Ulm 1846 (loan) (1987-1988)

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọdun 1988 ni Samuel Okwaraji kọkọ gba bọọlu fun orilẹede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ Afrika ninu eyi ti o ti gba ọkan lara awọn goolu to yara wọle ju lọ ninu itan idije naa.

Ṣe wọn ni iku ogun nii pa akinkanju, oju ija, iyẹn lori papa ni Samuel Okwaraji ku si lasiko ifẹsẹwọnsẹ fun ati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni ọdun 1990. Ifẹsẹwọnsẹ naa waye ni ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 1989 pẹlu orilẹede Angola.

Ka ni Okwaraji ko ku ni, oni yii, ni ko ba pe ọmọ ọdun marundinlọgọta lori oke erupẹ.