Atiku fẹ́ fa Lauretta Onochie, amúgbálẹ́gbẹ́ Buhari, lọ silé ẹjọ́ fún ọ̀rọ̀ orí Twitter, ó tún bèèrè fún N500m

Lauretta tó jẹ́ amúlẹ́gbẹ́ Buhari Image copyright LAURETTE ONOCHIE
Àkọlé àwòrán Lauretta Onochie

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fun idibo aarẹ to kọja Atilu Abubakar ni oun yoo fa ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari Lauretta Onochie lọ ile ẹjọ ti ko ba san owo itanran fun oun. O ni o pa irọ mọ oun lori Twitter.

Ninu iwe ti agbẹjọro Atiku, amofin agba Mike Ozekhome kọ si Onochie, eyi to fi ṣowo si awọn oniroyin, Atiku ni Onochie pa irọ mọ oun wipe awọn agbofinro n wa oun fun awọn ẹsun kan ni orilẹede UAE.

Nitori eyi, Atiku ti ni ki o san owo itanran miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta tabi ko fi oju ba ile ẹjọ nibi ti oun yoo ti wa beere biliọnu meji fun ẹsun pe o n du kooko mọ oun lori ayelujara.

Atiku ni yatọ si owo itanran yii, ki Onochie tọrọ aforiji lọwọ oun ninu iwe iroyin mẹfa laarin ọjọ meji. Bi ko ba ṣe bẹẹ, o ni oun yoo gbe lọ ile ẹjọ.

Onochie jẹ oluranlọwọ aarẹ Buhari lọri ọrọ itakun ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro

Orilẹede Naijira ti fofin de didun kooko mọni lori ayelujara ni ọdun 2015 nigba ti aarẹ Buhari buwọ lu abadofin naa.

Ofin naa ṣalaye wipe ẹnikẹni to ba pa irọ mọ ẹlomiran tabi to sọ oun ẹgbin ti ko ni ẹri kankan nipa ẹlomiran lori ayelujara yoo foju wina ofin, to si lọ lọ ẹwọn nitori bẹẹ.