May 29, 2019: Láti 1999 títí di 2019, wo àwọn ààrẹ tó jẹ ní Nàìjíríà

Laarin ọdun 1999 si ọdun 2019, aarẹ mẹrin ọtọọtọ lo ti dari orilẹede Naijiria latigba ijọba awa ara wa.

Olusegun Obasanjo

Àkọlé àwòrán Oloye Olusegun Obasanjo

Olusegun Mathew Okikiola Aremu ni aarẹ ikarun ati ikejila to jẹ lorilede Naijiria.

lusegun Obasanjo jẹ ajagunfẹyinti to jẹ aarẹ Naijiria laarin ọdun 1999 si 2007 fun saa meji.

Obasanjo ti ṣaaju jẹ ologun ko to ṣe ijọba gẹgẹ bi olori orilẹede lẹẹmeji .

O jẹ aarẹ labẹ ijọba ologun lati ọjọ kẹtala oṣu keji ọdun 1976 si ọjọ kinni oṣu kẹwa ọdun 1979.

Lẹyin eyi o di aarẹ labẹ ijọba awa ara wa laarin ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kaarun ọdun 1999 si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2007.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Lasiko iṣejọba rẹ, o da ajọ meji to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra silẹ - EFCC ati ICPC.

Ni ọdun 1958 ni Olusegun Obasanjo dara pọ mọ awọn ologun Naijiria lati igba naa lo si ti ni oniruuru imọ ẹkọ ogun.

Oniruuru ipo ni Obasanjo ti di mu gẹgẹ bi ọgagun to si ti kopa ninu ọpọlọpọ eto to ni ṣe pẹlu ijagun nile ati lẹyin odi.

Lẹyin to gba igbega si ipo adari ọwọ ogun (Captain) lọdun 1962, o lọ kawe kun iwe ni Royal College of Military Engineering, Chattam ni England.

Obasanjo tun gba igbega si ipo lieutnant colonel lọdun 1967 wọn si fi ṣe adari ẹkun kaakiri orilẹede Naijiria.

Wọn gbiyanju lati tun ofin 'se k'Ọbasanjo ba le ṣe saa kẹta sugbọn ile asofin ko gba a wọle lọdun 2007.

Ọjọ karun oṣu kẹta ọdun 1937 ni wọn bi Olusegun Matthew Okikiola Aremu Obasanjo.

Umaru Musa Yar'adua

Àkọlé àwòrán Ààrẹ Umaru Musa Yar'adua

Umaru Musa Yar'adua ni aarẹ ikẹtala to jẹ lorilẹede Naijiria.

Yar'adua ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Katsina ni iha ariwa orilẹede Naijiria laarin oṣu karun ọdun 1999 si oṣu karun ọdun 2007.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nii ṣe. Wọn kede rẹ gẹ́gẹ́ bi ajawe olubori fun ipo aarẹ lọj kọkanlelogun oṣu kẹrin ọdun 2007 ti wọn si bura wọle fun un ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun dun kan naa.

Iran Fulani ni Musa Yar'adua lati ilu Katsina, baba rẹ ti jẹ Minisita fun ilu Eko ri nigba ti Naijiria ṣẹṣẹ gba ominira. Yar'adua jogun oye Matawalle (alabojuto ẹṣọ ile oye) eyi ti baba rẹ ti jẹ ṣaaju.

Fasiti Ahmadu Bello ti Zaria ni o ti kẹkọọ gboye onipele ikinni ati ikeji.

Alhaji Umaru Musa Yar'adua gbe Turai niyawo lọdun 1975 wọn si ni ọmọ meje - obinrin marun ati ọkunrin meji.

Yar'adua fẹ Hauwa Umar Radda ni iyawo keji lọdun 1992 ti wọn si ni ọmọ meji.

Oun ni aarẹ Naijiria akọkọ to kede dukia rẹ ni kete to de ipo lọdun 2007.

Wọn bi Musa Yar'adua ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ ọdun 1951, o papoda lẹyin aisan pipẹ lọjọ karun oṣu karun odun 2010.

Godluck Ebele Jonathan

Àkọlé àwòrán Ààrẹ Goodluck Ebele Jonathan

Goodluck Ebele Jonathan kawe gboye ni ile iwe giga fasiti ilu PortHarcourt, o gba oye ipele keji ati oye PhD ni fasiti kan naa.

Ko to dara pọ mọ oṣelu lọdun 1998, Jonathan ti jẹ oṣiṣẹ ọba ni ile iṣẹ to n ri si ọrọ ayika.

O jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa lọdun 1999 ni wọn bura wọle fun un gẹgẹ bi igbakeji gomina si gomina Diepreye Alamieyeseigha labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

O di igbakeji aarẹ Umaru Musa Yar'adua lọdun 2007 nigba ti wọn bura wọle fun un gẹgẹ bi aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'OPC ko ṣ'atilẹyin fun Jonathan ni 2015'

Ẹwẹ, ni ibamu pẹlu ilana igbejọba le ni lọwọ ninu ofin orilede Naijiria, lẹyin iku aarẹ Musa Yar'adua lọjọ karun oṣu karun ọdun 2010, wọn bura wọle fun igbakeji aar Goodluck Jonathan gẹgẹ bi adele aarẹ orilede Naijiria.

Eyi lo sọ ọ di aarẹ ikẹrinla orilẹede Naijiria. O jẹ ko di mimọ pe oun wọ iṣẹ ninu iṣẹlẹ ibanujẹ ati eyi to da yatọ.

Ọjọ kẹẹdogun osu kẹsan ọdun 2010, Jonathan kede loju opo facebook pe oun ti pinu lati du ipo aarẹ fun igba akọkọ.

Labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Goodluck Jonathan figagbaga pẹlu igbakeji aarẹ tẹlẹ ri, Atiku Abubakar t'oun naa n du ipo aarẹ.

Ọjọ kẹtala oṣu kini ọdun 2011 ni wọn kede Jonathan gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ti Namadi Sambo si di igbakeji rẹ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Muhammadu Buhari

Àkọlé àwòrán Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ààrẹ Muhammadu Buhari ni ààrẹ ikeeje ati ikẹẹdogun ti orilẹede Naijiria ti wn yoo bura wọle fun ni ọjọ kọkandinlogun oṣu karun-un dun 2019.

Nigba ti idibo ọdun 2019 ti wa to ti lọ, Aarẹ Buhari jawe olubori lẹẹkan sii gẹ́gẹ́ bi aarẹ Naijiria.

Idibo ti ọdun 2015 jẹ eyi to laami laaka gẹgẹ bi Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo ṣe polongo pẹlu ileri 'ayipada' ni ibo to le ni miliọnu mẹẹdogun lati jawe olubori ninu idibo naa.

Muhammadu Buhari gba oye Grand Commander of the Fedral Republic (GCFR) ati ọpọlọpọ oye idalọla mii.

Oloye Fulani kan ni baba rẹ jẹ ti orukọ iya rẹ si n jẹ Zulaihat. Oun ni ikẹtalelogun ninu ọmọ baba rẹ.

Lati nkan bi ọmọ ọdun mẹrin lẹyin ti baba rẹ ku ni iya Buhari ti n tọ ọ titi ti o fi dagba.

Muhammadu Buhari jẹ oloṣelu a si le ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn gbajugbaja oloṣelu tẹsẹ wọn rinlẹ ni iha Ariwa orilẹede Naijiria.

Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ Aisha Muhammadu Buhari to j obinrin akọkọ ni Naijiria, Ọlọrun si fi ọmọ ati ọmọ ọmọ ta wọn lọrẹ.

Wọn bi Aarẹ Muhammadu Buhari ni idile ẹya Fulani kan ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun 1942 ni ilu Daura ipinlẹ Katsina.

Related Topics