Naira Marley: Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa rẹ̀

NAira Marley Image copyright Instagram/@nairamarley
Àkọlé àwòrán NAira Marley

Azeez Fashola ti inagijẹ rẹ lori itage n jẹ Naira Marley jẹ olorin Naijiria to ṣẹṣẹ n goke.

Rayin rayin lorukọ rẹ n ja lori awọn iroyin Naijiria ati ilẹ Afirika bayii to bẹẹ́ to jẹ wi pe orukọ rẹ gba ori ẹrọ ayelujara kan.

Ọwọ ofin tẹ ẹ gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe gbe e lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe o n jale lori ẹrọ ayelujara eyi ti gbogbo eniyan mọ si "Yahoo Yahoo".

Oun pẹlu Zlatan t'oun naa jẹ olorin ni wọn fi panpẹ ọba mu. NAira Marley ti de ile ẹjọ lati ibẹ wọn tun ti gbe si ahamọ ọlọpaa.

Diẹ lara ohun ti ẹ le ma mọ nipa olorin to tun ti n di gbaju gbaja latari ẹsun ti wọn fi kan an niyii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'
  • Ọjọ kẹwa oṣu karun ọdun 1991 ni wọn bi i to si dagba ni agbegbe Agege ni ipinlẹ Eko.
  • Ni ọmọ ọdun mkanla lo ko lọ si ilẹ UK lati maa gbe nibẹ
  • O ti di ọmọ ilu ọba to ni iwe igbe ilu labẹ ofin bayii bẹẹ lo si tun jẹ ọmọ Naijiria nipa ìbí.
  • Iṣẹ atọkun ariya tabi ayẹyẹ (MC) lo n ṣe tẹlẹ ko to bẹrẹ orin kikọ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Nígbà tí mò ń wà Awolowo, Gowon, Babangida, mo fi ara mi sípo ọ̀wọ̀ tóri ...'
  • Ọjọ kẹwa oṣu karun ni ajọ EFCC mu u laipẹ.
  • Naira Marley funra rẹ polongo pe ọpọlọpọ igba ni wọn ti fi oun jofin ni ilẹ Gẹẹsi.
  • Ọrẹ timọ timọ Zlatan Ibilẹ ni ti wọn mu wn papọ ati Rahman Jago, Guccy Branch ati ẹlomiiran.
  • Marley gbajugbaja fun orin rẹ, to n milẹ titi nigboro "Issa Goal".

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ lè nífẹ sí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì