PDP vs Tinubu: Aṣíwájú Tinubu lọ́ra láti fi wá kọ́ èébú

Tinubu Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Asiwaju Ahmed Tinubu fẹ̀sùn kan PDP pé wọ́n fẹ́ fi tipátipá mú Atiku Abubakar jẹ ààrẹ orílẹ̀èdè Naijiria.

Ẹgbẹ oselu PDP ti ke si adari ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Aṣiwaju Ahmed Tinubu lati tọwọ ọmọ rẹ bọṣọ lori bi o ṣe n tẹnu bọlẹ lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ni oju opo ikansiraẹni Twitter wọn, PDP ni aṣiwaju n fi awọn kọ eebu pẹlu bi o ṣe gbẹra lati orilẹede Naijiria lọ si Mecca lati lọ ba Aarẹ Buhari sọrọ kubakungbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá

PDP bu ẹnu atẹ lu Asiwaju Tinubu pe o fẹsun kan ẹgbẹ oselu PDP ati oludije sipo aarẹ lẹgbe oselu naa, Atiku Abubakar wi pe wọn fẹ fi tipatipa gbe e wọle gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria.

Bakan naa ni wọn ke si ẹgbẹ oselu APC wi pe ki o ba adari rẹ sọrọ ko ye tẹnubọlẹ kiri mọ gẹgẹ bi agba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'