Plastic Bags: Kíni ìdí tí wọn fi fẹ́ fòfin de lílo nylon ní Naijiria?

Nylon Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ile igbimọ asojusofin lorilẹede Naijiria ti fi ontẹ lu abadofin to fopin si lilo rọba tabi nylon ni Naijiria.

Ile igbimo asojusofin lorilẹede Naijiria ti buwọlu abadofin to fi le le pe ẹni to ba lo nylon yoo fi ẹwọn ọdun mẹta jura.

Ile igbimọ asofin naa lasiko ti wọn n fi abadofin naa le le ni yoo koju ijamba ti lilo nylon tabi rọba n se si awọn ẹja inu okun, eniyan ati agbeegbe naa.

Amọ ti aarẹ ba buwọlu u yoo mu abadofin naa da ofin, nitori naa a le lo iwe lati fi se awọn ohun elo ti a le gbe nkan si inu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A fẹ́ kí àwọn sẹ́nétọ̀ gba ẹlòmíì láàyè'

Kini idi ti wọn fi fẹ fofin de lilo nylon ni Naijiria?

Image copyright Getty Images

Awọn onimọ nipa eto ayika ti sọ wi pe ijamba ti lilo nylon tabi rọba n se si ayika pọju anfaani to n se lo. Ninu awọn ijamba ti wọn sọ ni yii:

 • Lilo nylon n ba ayika jẹ nitori ọpọlọpọ eniyan to ba lo o, ni wọn ma n ju u si ilẹ tabi inu omi eleyii ti o ma n di oju ọna ti omi n gba kọja.
 • Ohun elo ti wọn fi n se awọn nylon ati rọba jẹ ohun to n ba oju ọjọ jẹ, eleyii ti wọn n pe ni ‘polyethylene’.
 • Nylon ati rọba ki n kere ju bi o ba se wa nigba ti wọn se e fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, eleyii ti o le ko aisan mọra lẹyin ọpọ ọdun loju kan naa.
 • Awọn ẹja inu odo ati awọn ẹranko inu okun ma n jẹ nylon ati rọba ti wọn ba ri i nitori o dabi ounjẹ, amọ iku lo jẹ fun wọn.
 • O soro lati se atunlo nylon tabi rọba kuro ni ohun elo kan si omiran
 • A ti ra nylon ati rọba jẹ owongogo, bẹ ẹ naa ni ati ko wọn kuro nilẹ lẹyin ti awọn eniyan ba lo wọn.

Awọn orilẹede ti wọn ti fofin de lilo nylon

Bangladesh lo kọkọ fofin de li lo rọba tabi nylon ni ọdun 2002. Awọn orilẹede ti wọn ti se bẹẹ ni:

 • Kenya
 • Rwanda
 • South Africa
 • Morocco
 • Taiwan
 • New Delhi
 • France
 • Montreal
 • China
 • Israel
 • Netherlands
 • Mauritania
 • Sri Lanka
 • Papua New Guinea,
 • Vanuatu
 • Albania
 • Georgia