Àwọn dókítà LUTH daṣẹ́ lẹ̀ ṣè ìwọ́de lórí àìsí ààbò

Awọn dokita LUTH to n ṣe iwọde

Awọn dokita ile iwosan ikọsẹ iṣegun ti ijọba apapọ to wa ni Ipinlẹ Eko, LUTH, ti da irinṣẹ silẹ lati ṣe iwọde loni.

Won n fẹhonu han lori aisi aabo fun awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa.

Bakan naa ni wọn tun n fẹhonu han lori owo oṣu ti wọn jẹ wọn pẹlu awọn wahala miiran ti wọn ni o wa nile iwosan naa.

Ṣugbọn, adari ile iwosan naa, Ọjọgbọn Chris Bode ti Ọjọgbọn Olufemi Fasanmade ṣe agbẹnusọ fun, ni ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan naa pinnu lati daṣẹ silẹ nitori wipe wọn jawe ikilọ fun awọn kan lara wọn nitori iwa to ku diẹ kaato ti wọn hu.

Pẹlu akọle lọwọ ni awọn dokita naa fi wọde kaakiri agbegbe Idi Araba nibi ti LUTH tẹdo si ni Idi-Araba ni Ipinlẹ Eko.

Oṣu to lọ ni awọn ole pa dokita ile iwosan naa kan, Stephen Urueye, ninu ọgba ile iwosan naa.

Ko pẹ lẹyin rẹ ni Ọwọ Ọlọ́pàá tẹ afunrasi méjì tó mọ nípa ikú dókítà LUTH naa.

Ọjọ meji lẹyin ti dokita naa pari ẹkọ rẹ ni awọn agbebọn naa gbẹmii rẹ.

Bakan naa ni awọn dokita naa ni ọpọlọpọ awọn nkan ti o lemu iṣẹ wọn dẹrun ni ko si nile iwosan naa.

Aipẹ yii ni Ile Igbimọ Asofin Agba fiwe pe Minisita fun Eto Ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewọle, ti wọn si ni ko ṣalaye idi ti nkan ko fi lọ deede ni awọn ile iwosan ijọba apapọ to wa ni orilẹede yii bi ti LUTH.

Minisita naa to lọ farahan niwaju awọn aṣofin ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun un, ni ọrọ owo ni o n jẹ awọn ile iwosan naa ni iya.

Image copyright Then Nigerian Senate

Adewọle ni, "Ero ti pọ ju ibi ti agbara awọn ile iwosan naa le gbe lọ.

Ko si amojuto fun iwosan alabọde, eyi to fi jẹ ki gbogbo eniyan maa wa si awọn ile iwosan ikọṣẹ iṣegun.

Ida mẹwa ninu ọgọrun ọmọ Naijiria nikan ni o yẹ ko maa lọ si ile iwosan ikọsẹ iṣegun, ṣugbọn wọn ko ni ifọkanbalẹ lori iwosan alabọde mọ."

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsigbe awọn ọmọkunrin meji ni India