'Olódo ni mí nílé ìwé kí n tó ṣàwárí ẹ̀bùn mi'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Contortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí pẹ́!

Ara mi rọ̀, kò si bí mi ò ṣe lè ká ẹsẹ̀ mi- Oyindamola.

Kò sí iṣẹ́ ti èèyàn kò lè yàn láàyò ni kete ti o ba ti ṣawari ẹbun ti Ọba òkè fi jinki rẹ.

Oyindamọla Kọlawọle Emmanuel ti o n lọ́ ẹran ara rẹ ati egungun rẹ fi da àrà to wùú, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'Contortionist' ṣalaye ohun to ṣokunfa eyi fun BBC Yorùbá.

O ni aimọwe ohun daadaa nile ìwé lo jẹ ki oun ronu ọna miran ti oun fi le wulo lawujọ Yoruba gẹgẹ bii ọmọ Oodua gidi to fẹ gbe aṣa ga.

Oyindamola sọrọ lori awọn ami ẹyẹ ti oun ti gba ati awọn aṣeyọri to ti ni lẹnu yiyan iṣẹ yii laayo.

O mẹnuba bi oun ṣe bẹrẹ pẹlu ijo ibilẹ nile iwe nibi ti oun ti rii pe ara oun ṣeé rọ́ si ipokipo tó bá wu oun.

Oyindamọla ni oun ṣetan lati maa kọ awọn ewe iwoyi ni iṣẹ yii ko lè tubọ jẹ itẹwọgba sii lawujọ Yoruba.

O gba awọn ọdọ nimọran pé ki wọn ṣawari ẹbun ti Ọlọrun fun wọn nitori kii ṣe gbogbo eyan lo maa fi iwe kika jẹun bi igboro ṣe ri lasiko yii.