Nigeria Police Force: Buhari f'òǹtẹ̀ lu Mohammed Adamu gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun.

Aarẹ Buhari ati adele ọga ọlọpaa Adamu Image copyright @Bashir Ahmad

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu iyansipo Mohammed Adamu gẹgẹ bi ọga ọlọpaa tuntun fun orilẹede Nàìjírìa.

Oluranlọwọ aarẹ lori ayelujara, Bashir Ahmad fidi ọrọ naa mu lẹ loju opo Twitter rẹ pe Aarẹ Buhari gbe igbesẹ lẹyin ipade igbimọ ọlọpaa nile ijọba l'Abuja l'Ọjọbọ.

Aarẹ BUhari fun ra rẹ lo dari ipade ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Nígbà tí mò ń wà Awolowo, Gowon, Babangida, mo fi ara mi sípo ọ̀wọ̀ tóri ...'

Lọjọ kẹẹdogun oṣu kinni ọdun yii ni aarẹ kọkọ yan Ọgbẹni Adamu gẹgẹ bi adele fun ọga ọlọpaa Naijiria tẹlẹ, Ibrahim Idris to fẹhinti.

Ki aarẹ to yan an sipo, Ọgbẹni Adamu jẹ igbakeji ọga ọlọpaa, to si n ṣiṣẹ nile iwe ọlọpaa to wa ni ilu Kuru, nipinlẹ Plateau.

Gbogbo gomina ipinlẹ mẹrindinloji ni Naijria pẹlu miniita ọrọ abẹle, Ajagun Fẹhinti, Abdulraham Dambazau lo peju sibi ipade naa.

Ko da alaga ajọ to n ri si ọrọ ọlọpaa, Ọgbẹni Musiliu Smith ati akọwe agba ajọ naa, Ọgbẹni Mbaeri Maurice Nnamdi naa ko gbẹyin nibi ipade ọhun.