'Fún ìtẹ̀síwájú ìpínlẹ̀ Kwara ni wọ́n ṣe ni Ó tó gẹ́!'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Abdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Màá lọ mojuto àwọn ilé iṣẹ́ aládani mi ni bayii- Abdulfatah Ahmed.

Igba kan n lọ, igba kan n bọ, ẹnikan ko lo ilé aye gbo ni awọn Yorùbá n wi.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni awọn to wa nipo bayii a kogba wọle ti awọn ojú tuntun a gori aleefa ni awọn ipinlẹ Naijiria.

Gomina Abdulfatah Ahmed lo ti tukọ ipinlẹ Kwara fun ọdun mẹjọ gbako labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) naa wa lara awọn to n kogba wọle.

Gomina Abdulfatah ba BBC Yoruba sọrọ pé ohun to kuku n tan lọdun eegun ni ọrọ oṣelu.

Oludije ti ẹgbẹ PDP fa kalẹ, Razak Atunwa ni oludije ẹgbẹ APC, AbdulRazak Abdulrahman fidi ẹ janlẹ ninu eto idibo Naijiria to kọja.

Gomina Ahmed sọrọ kikun lori idi ti awọn eniyan Kwara fi yan ẹgbẹ oṣelu miran ninu idibo to kọja fun BBC Yoruba.

O ni a ko le sọ pe oju kan ni ki nkan maa lọ lagbo iṣelu lagbaye.

Abdulfatah ni oun to ṣẹlẹ ni pe awọn eniyan Kwara ro pe o ni ipa miran to yẹ ki igbimọ ẹgbẹ to n fa ijọba kalẹ ni Kwara gbe ni.

O ni o da oun loju pe awọn eniyan Kwara a mọ iyatọ iṣejọba mejeeji laipẹ laijinna.

Bakan naa lo sọrọ oko rẹ àti iṣẹ aladani ti oun n pada si ni kete to ba ti kuro nijọba ati pe ọrọ oṣelu ko ṣee kọ̀ silẹ.

O ni awọn a jọ maa ṣe iṣelu lọ ni.