Àwọn agbábọ́ọ̀lù Nààijíríà tí wọ́n kàgbákò oníjìbìtì
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Footballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé

Ireti òbí àti alágbàtọ́ ti n wọ̀ọkùn lórí àṣeyọri ọmọ wọn to n gba bọọlu.

Ọpọlọpọ àwọn ọdọlangba agbabọọlu Naijiria lo wu wọn lati maa gba bọọlu fun ẹgbẹ nilẹ okeere ṣugbọn awọn onijibiti kan n fi wọn jẹun lasan ni.

BBC Gist Naija ṣe iṣẹ iwadii lori awọn ti wọn ti bọ sọwọ agbewiri, o jẹ ohun to yanilẹnu pe ọpọlọpọ ni wọn ti kagbako awọn aṣoju agbabọọlu ti wọn jẹ gbajuẹ.

Diẹ lara awọn agbabọọlu ti wọn ti ko sọwọ ti wọn ba BBC sọrọ ni Micheal Ọbumneme, Emmanuel Clement, Idowu Oluwole Julius atawọn mii.

Iwadii BBC fihan pe awọn agbabọọlu yii wa lati oriṣii orilẹ-ede ni, kii ṣe Naijiria nikan.

BBC tun rii pe àwọn orilẹ-ede bii India, Denmark, Iran, Srilanka, Russia ati ilẹ̀ Europe ni wọn fi n parọ fawọn ọmọ wọnyii pe wọn a ko wọn lọ lati maa gba bọọlu jẹun.

Bẹẹ gbogbo obi ati alagbatọ lo n wa ọna atijẹ fawọn ọmọ wọn ati igbe aye to dara.

Eyi lo n jẹ ki wọn maa tiraka lati wa owó ti awọn aṣoju yii ba beere fun ti wọn si fi n ko sọwọ gbajuẹ.

Ni ipari wọn gba pe afi ki ijọba fi ofin de awọn oniṣe ibi yii kawọn ọdọ wa yee ko si ọwọ wọn lataari ifẹ ere bọọlu ni gbigba.

Vedio Producer: Ajoke Ulohtse