Ìjọba Buhari kìí ṣe ọ̀nà àbáyọ síṣòro Naijiria-Jiti Ogunye
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Jiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Ọ̀rọ̀ Naijiria tojú súni -Jiti Ogunye, àgbà ọjẹ agbẹjọrọ ni Naijiria.

Jiti Ogunye ṣalaye fun BBC Yoruba pé Naijiria ti n di ọlá n rẹyin nitori pe ọla wa ko lọ siwaju mọ ni gbogbo ọna.

Ajafẹtọ ọmọniyan yii gba pé awọn ipinlẹ pupọ ti ijọba ologun da silẹ lo faaye gba oloṣelu lati maa jẹ ìlú lasiko yii.

Amofin Jiti Ogunye bẹnu ẹ̀tẹ́ lú owó inakuna to pọju laarin awọn oloṣelu lasiko yii.

O ni oloṣelu ti ba ijọba jẹ de gongo bẹrẹ lati ipele ijọba mẹtẹẹta.

Ajafẹtọ ọmọniyan yii gbe awọn ẹka aṣeyọri Naijiria sori oṣuwọn lati ogun ọdun sẹyin ti a ti n ṣe ijọba alagbada.

Jiti ni a ko pegede rara ninu ibọwọ fun ofin, eto ọrọ ajé, ilera, eto ẹkọ, eto aabo, ati ẹtọ ọmọniyan.

O ni awọn oloṣelu ti wọn jẹ ọ̀jẹ̀lù yii ti ba owo Naijiria jẹ debi pe o ti àkísà lawujọ owó ni agbaye àti pe ọpọ ẹmi ati dukia lo n sọnu nigba ti ijọba ko gbe awọn igbese to yẹ ni gbigbe fun ilọsiwaju.

Ni ipari, Jiti Ogunye ta awọn eniyan Naijiria jí pé ọwọ wa ni agbara wa lasiko yii.

O ni ki onikaluku dẹkun ibo tita, ki wọn jade gbaruku ti ẹni to ṣetan lati sin ara ilu yatọ si ifẹ inu wọn.

Bakan naa lo ni ki a dẹkun sisọ ara wa si oko ẹru awọn oloṣelu nitori owo ti ko tan iṣoro wa.