Zamfara INEC ti kéde pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló jáwé olúbori nínú ìdìbò 2019

Ile iṣẹ́ INEC Image copyright INEC
Àkọlé àwòrán Zamfara INEC ti kéde pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló jáwé olúbori nínú ìdìbò 2019

Ilé iṣẹ́ àjọ elétò ìdìbò órílẹ̀-èdè Nàijirià lọ́jọ́ sátide ti kédé àwọn olùdíje ọmọ ẹgbẹ̀ alatako ni Nàijiria PDP gẹ́gẹ̀ bi ẹni to jáweé olúbori nínú ìdìbò gómìnà àti ile ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Zamfara ti ọdun 2019 to wáye.

Ǹkan ti àjọ eleto ìdìbò ṣe ni pé wọn tẹ̀lé ìdájọ ilé ẹjọ to ga julọ tó jẹjọ náà ni ọjọ jimọ, èyí to sọ pe ìbò ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ]ipínlẹ̀ náà ko fẹsẹ múlẹ̀ ni ìpínlẹ̀ náa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Ọ̀gá àgbà àjọ INEC ọjọgbọ́n Mahmood Yakubu to kede ìjáwe olubori ọhun sàlàye pe ìjẹjọ ilé ẹjọ to ga jùlọ to wáye ni àná ọjọ Jimọ ló mu ki àwọn yí ìkédé ẹni to jáwe olúbolri páda kuro ni APC ti àwọn ti kede tẹlẹ si PDP.

Ọ̀gá Yakubu sọ pé àjọ INEC yóò fún gbogbo wọn ni ìwé èrí ní ọjọ ajé ti ṣe ọjọ kẹtàdinlọgbọ̀n oṣù kàrún ọdun 2019.

Lásìkò ìkéde yìí alága INEC kéde Bello Muhammad Mutawalle to jẹ olùdíje PDP fun gomina gẹ́gẹ́ bi ẹni to jáwe olúbori ní Zamfara.

Ní ti ilé ìgbìmọ aṣòfin àti ilé ìgbìmọ aṣofin ìpínlẹ̀ ti ko mu wahala dani, bio se ti gomina, A ni láti wo àwọn ti o pọ jùlọ tó si jẹ Bello Mutawalle lo jáwe olubori.

Alaga INEC sàlàye pé lẹ́yin ti àwọn ti fi gbèdèke fún ìdìbò abẹlé APC ti wọn o si mu èsì ìdìbò abẹle ti won wa ni àwọn o fi ka wọn kún ti wọn si gbe ẹjọ lọ si ilé ẹjọ.