Ẹ̀rù ogun n bà mí fún ìran Yorùbá -Bode
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Bode George: Ọkanjua lo n yọ Tinubu lẹnu

Agba ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), oloye Bode George se ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin nilu Eko.

Nibẹ lo ti dahun ibeere loriṣiiriṣii lori eto oṣelu Naijiria ati bi nkan ṣe ri lasiko yii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bode George ni Tinubu kò mọ pé ebi n pa àwọn ara ilu rara.

O ni loju toun Asiwaju Tinubu n ko ọrọ ipinlẹ Eko pamọ ni.

Lasiko to n dahun ibeere lori bi awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ṣe n yalọ si ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii, Bode George ni ẹgbẹ mejeeji yatọ sira wọn.

O ni wọn a to rii pé ayé pé meji nitori ominira ti wọn n ri ni PDP ko le tete tẹ wọn lọwọ ni APC ti wọn lọ.

Nigba ti Bode George n dahun ibeere lori ayajọ iṣẹjọba Alagbada ti Democracy Day tọdun 2019, o ni iran Yoruba ni lati kọgbọn sii fun itẹsiwaju to yẹ.

Yoruba ni Bọmọ ko ba ba itan, o maa n ba arọba to jẹ baba itan, Bode George ni asiko ti to ki a ma kọ awọn nipa ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni June 12 ati May 29.