Asset Declaration: Buhari, Osinbajo ti fi fọ́ọ̀mù ìkéde Dúkìá sọwọ́

Aarẹ Buhari àti Igbakeji rẹ Osinbajo Image copyright @ProfOsinbajo, Getty Images‏
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari àti Igbakeji rẹ Osinbajo

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi iwe ikede dukia ti o gba ṣọwọ pada si ajọ to n boju wo dukia awọn to di ipo nla mu niluu, Code of Conduct lọjọ aje ọjọ kejidinlọgbọn.

Eyi ni lati ba gbedeke ti ajọ naa gbe silẹ fun awọn oṣiṣẹ ọba lati wa kede dukia wọn ki saa iṣejọba ti wọn wa to pari.

Gẹgẹ́ bi o ṣe wa ninu ofin, kikede dukia pọn dandan ṣaaju eto ibura wọle rẹ eyi ti yoo waye lonii ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

"Ẹkunrẹrẹ fọọmu ti idahun ti wa ninu rẹ ni Sarki Abba to jẹ oluranlwọ́ pataki fun aar lori ọrọ inu ile lorukọ aarẹ Buhari fi sọwọ si alaga ajọ CCB, Ọjọgbọn Mohammed Isa". Eyi ni ọfiisi aarẹ sọ lalẹ ana ninu ọ̀rọ̀ oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Garba Shehu.

Aarẹ ni "ko si ile tuntun, ko si afikun apo isuna ni banki nile ati lẹyin odi mi o si ni ipin idokoowo kankan to kun awọn ohun ti mo ni tẹlẹ".

Ni ifesi, alaga ajọ CCB naa ti gboriyin fun aarẹ pe o jẹ ẹṣin iwaju ti tẹyin n wo sare pẹlu bi o ṣe kede dukia rẹ ni ilana to ba ofin mu.

Lori ẹsun pe aarẹ ni ẹgbọrọ maalu to fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún niye, aguntan bọlọjọ mẹẹdọgbọn, ẹsin marun-un, ẹran ọsin abiyẹ ati igi to n pawo wọle to fi mọ ile marun-un ni Kaduna, Daura, Kano, Abuja.

Buhari ni awọn ile ti Daura, "àmọ̀ ni wọ́n fi kọ́ ọ".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ni ti igbakeji aarẹ Ọjọgbọn Osinbajo, "nigba ti a gbe fọọmu naa yẹ wo, ko si ayipada kan sàán to yatọ si ohun ti a kede lọdun mẹrin sẹyin". Alabukun fun ni naijiria pẹlu aarẹ ati igbakeji to fi ootọ inu ṣe ọkunkundun." Eyi ni atẹjade agbẹnusọ igbakeji aarẹ Osinbajo iyẹn Ọgbẹni Laolu Akande loju opo Twitter rẹ.

Awọn ile ti wọn ni o jẹ ti Osinbajo nigba naa ni wọn ka silẹ pe ile oniyara mẹrin ni Victoria Garden City nipinlẹ Eko, ile oni yara mẹta ni Mosley Road, Ikoyi l'Eko, ile oni yara meji ni Redemption Camp lopopona Eko si Ibadan ati ile oni yara meji to latọwọ eto san an diẹ diẹ ni Bedford, England. igbakeji aarẹ́ si tun kede awọn ipin idokoowo to ni. Lo ba tan!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?