Nigeria swearing-in: Ọjọ́ kò! Ìbúrawọlé Nàìjíríà ṣojú àgbáyé

Ogun
Àkọlé àwòrán Ogun

Latori ilu Abuja titi de gbogbo awọn ipinlẹ ti wọn ti dibo yan awọn adari ti yoo ṣoju awn ọm Naijiria ni saa iṣejọba tuntun yii ni eto ibura wọle yoo ti waye lonii.

Ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 209 ni idibo aarẹ ati tawọn aṣofin agba waye lorilẹede Naijiria ti ti awọn gomina ati aṣojuṣofin naa si waye ni ọsẹ meji tẹle e lẹyin ti wọn sun un siwaju kuro ni ọsẹ to tẹle ti aarẹ.

Àkọlé àwòrán Ibadan

Gomina Abdulfattah Ahmed ti ilu Ilorin ti wa nikalẹ ni olu ilu ipinlẹ̀ Kwara.

Àkọlé àwòrán Gomina Abdulfattah Ahmed ati iyawo rẹ

Emir ti ilu Ilorin, Alhaji Zulu Gambari wa nikalẹ ninu gbọngan iburawọle ni ilu Ilorin.

Àkọlé àwòrán Emir Zulu Gambari ti Ilorin

Awọn akọroyin BBC ti wa kaakiri orilẹede Naijiria lati maa mu iroyin lọlọkan o jọkan lori bo ṣe n lọ wa fun araye.

Igbaradi ti n rọ kẹkẹ ni gbagede Eagle square niluu Abuja atawọn ipinlẹ kọọkan.

Ni ipinlẹ Ogun, wamu wamu lawọn ologun ti duro.

Àkọlé àwòrán Abeokuta, Ogun

Ati ni ipinlẹ Oyo, awọn ologun ko kẹrẹ rara.

Àkọlé àwòrán Ibadan

Awọn ara ipinlẹ Kwara ti wa nikalẹ ni gbngan igbalejo ijọba ipinlẹ to wa ni ilu Ilorin.

Àkọlé àwòrán Ilorin

Adajọ agba ti yoo bura wọle fun gomina tuntun ni ipinlẹ Kwara, Alhaji Durosinlohun Kawu ti wa nikalẹ.

Àkọlé àwòrán Adajọ agba Durosinlohun Kawu

Ni ilu Ibadan, ijo ibilẹ ni wọn fi n ki awọn eniyan kuabọ si gbọngan ti iburawọle yoo ti waye ni ilu Ibadan.

Àkọlé àwòrán Ibadan
Àkọlé àwòrán Kwara

Awọn ladelade-loyeloye, tofimọ awọn aṣaaju ẹsin ti wa nikalẹ ni papa iṣere Liberty Stadium nibi ayẹyẹ ibura fun gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn a ṣi n reti gomina tuntun, igbakeji rẹ ati awọn adari ẹgbẹ Oṣelu PDP

Àkọlé àwòrán Oyo, Ibadan

Awọn gbalẹ gbalẹ gan n ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ ni gbagede iburawọle ti ipinlẹ Ogun.

Àkọlé àwòrán Abeokuta, Ogun

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin bo ṣe n lọ jakejado Naijiria.