Irú ọmọ wo ni Yorùbá máa ń pè ní Ìgè?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

BBC Yorùbá jáde bèèrè irúfẹ́ ọmọ ti Yorùbá n pè ni Ìgè.

Orúkọ Amutọrunwa jẹ ọkan lara orukọ ti iran Yoruba maa n sọ ọmọ wọn yatọ si orukọ abísọ, orukọ ẹ̀sìn, orukọ inagijẹ, oriki, orukọ idile ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Orukọ Amutọrunwa ni eyi to maa n ṣapejuwe ipo ti ọmọ naa wa bi a ṣe bii ni eyi to fihan ohun ti ọmọ naa n ṣe lati ọ̀run ni ikùn iya rẹ wa sile aye.

Ilé laawo ki a to sọ ọmọ ni orukọ ni igbagbọ awọn Baba nla iran Yoruba.

Ìdí ni yi ti wọn fi n sọ ọmọ ni orukọ lataari iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ lagboole, ninu ẹbi, ninu ilu lasiko ti a ba bi ìkókó.

Bẹẹ, orukọ ọmọ ni ìjánu ọmọ ni Yoruba kìí fi ṣàà déédé sọ ọmọ lorukọ ki orukọ.

Eyi lo fa owe: a sọ ọmọ ni Sódé, o lọ sajo o dé; A sọ ọmọ ni Ṣóbọ̀, o lọ sajo, o bọ̀; A wa sọ ọmọ ni Ṣorinlọ, ko wa pada wa sile mọ!

Wọn gba pe orukọ ọmọ lo máa n ro ọmọ.

Idahun si ibeere toni: Ige ni ọmọ ti o fi ẹsẹ̀ wa si ayé.

Ori ni ọmọ maa n saaba fi wa si aye ṣugbọn awọn kan maa n fi ẹsẹ wa ti Yoruba n pè ni Ìgè Àdùbí.

Ọpọ maa n gba pé ọdaju ọmọ ni wọn nitori ìbí wọn ṣeeṣe lati já si ikú fun iya wọn ti ko ba tete ri itọju to peye lasiko irọbi.

Sisọ ogidi ọmọ Yorùbá ni orukọ to ni itumọ kikun jẹ ọkan lara àṣà Yorùbá ti BBC kò fẹ ko parun.