World No Tobacco Day: Bí sìgá mímu ṣe kúrò ní òògun ìlera di ewu ńlá

Onimọ nipa ilera ọmọ Netherlands Everard, tabi Gilles Everaerts ni ede Dutch Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Onimọ ilera ọmọ Netherlands kan Everard gbagbọ pe taba lagbara to bẹẹ ti ko ni jẹ ki awọn dokita riṣẹ ṣe

Tábà wúlò púpọ̀ fún ìlera ẹ̀dá -Everad.

Fun ọpọlọpọ ọdun, siga mimu mu awuyewuye wa ni eyi to fi di ọrọ arugbo ṣoge ri, akisa lo ìgbà rí.

Oni, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un ọdun ni gbogbo agbaye ti tẹwọgba gẹgẹ bii ọjọ ayajọ pipa taba to ti jẹ oogun to dara fun ilera nigba kan ri rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Taba pe oriṣiriṣi ti wọn n ri l'agbegbe Amerika nibi ti awọn ara ilu ti n lo o gẹgẹ bii oogun ki awọn oyinbo alawọ funfun to de ibẹ

WHO sọ pé Taba n pa to ilaji awọn to n mu siga lọdun, eyi ti numba wọn to miliọnu mẹfa eniyan.

Iwadii ajọ WHO ni eniyan ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun eniyan ti ko mu siga ṣugbọn to n gboorun eefin siga ni o n ku ni ọdọọdun.

Fun ọpọlọpọ ọdun, siga jẹ oun to dara fun ilera, kóda àwọn kan tilẹ n pe taba naa ni "ewe mimọ" nigba kan.

Lati fi ero awọn eniyan han nigba kan, onimọ ilera ara Netherlands, Giles Everard ni igbagbọ pe taba lilo lagbara de ibi pé ko ni jẹ ki awọn dokita ri iṣẹ ṣe.

Ọjọgbọn Anne Charlton kọ itan pé Christopher Columbus tó jẹ ọkan lara awọn oyinbo alawọ funfun akọkọ to kọkọ ri bi wọn ṣe n lo taba fun iwosan.

Ni ọdun 1492 lo ri pe awọn ara ilu ti o di Cuba, Haiti ati Bahamas lonii n fi ikoko fa taba naa.

Image copyright Wellcome Collection
Àkọlé àwòrán Awọn oniṣegun alawọ funfun bẹrẹ si ni lo taba gẹgẹ bii oogun

Ati pé nigba miran, wọn n fi le kokoro to n fa aisan kuro ni agbegbe wọn.

Àkọlé àwòrán Sìgá mímu ń di èèwọ oògùn ìlera pípé lagbaye

Wọn tun n lo taba ti wọn po pọ mọ ṣọ́ọ́kì lati fi fọ ẹyin ni agbegbe to di Venezuela lonii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: Emi ati Ọbanikoro kii ṣe ẹgbẹ

Arinrinajo ara Portugal kan, Pedro Alvares Cabral lọ si Brazil ni ọdun 1500, nibi to ti rii pe wọn n lo taba lati fi tọju egbo wọn.

Image copyright Wellcome Collection
Àkọlé àwòrán Nigba kan awọn dokita oniṣegun n fi oorun taba bo awọn oku ti wọn fi n kọsẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNjẹ ọ mọ̀ pé mímí afẹ́fẹ́ tí kò dára lè fa àìsàn?

Awọn dokita alawọ funfun aye igba naa wá bẹrẹ si ni lo taba fun itọju oriṣiriṣi aisan.

Koda awọn onimọ to n fi oku kọṣẹ iṣegun maa n lo taba lati pa oorun oku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIparọwa si gbogbo awọn tọrọ naa kan lati ri wipe aba ofin naa mulẹ lorilẹede Naijiria

Nigba ti ajakalẹ arun bẹ silẹ ni London ni ọdun 1665, wọn ni ki awọn ọmọ wẹwẹ maa fa taba ni ile iwe.

Image copyright Wellcome Collection
Àkọlé àwòrán Eefin taba jẹ oun kan ti wọn fi koju ajakalẹ aarun 1665 ni London

Awọn to n sin oku bẹrẹ si ni fa taba lati le ajakalẹ arun lọ ni agbegbe wọn ni eyi to tun fi jẹ ki iwulo taba pọ sii.

Image copyright Wellcome Collection
Àkọlé àwòrán Nigba kan, taba jẹ ohun ti wọn maa n fun awọn ti wọn ba doola ẹmi wọn ninu omi lati jẹ ki ara wọn bọ sipo

Pẹlu bi awuyewuye ṣe pọ to lori rẹ taba di oun ti gbogbo aye n wa kiri nigba naa nitori pataki rẹ si ilera awọn ẹda.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIgbese ti ajo ERA gbe lati koju tita siga lagbegbe ile ẹkọ

Ti eti ba n dun eniyan, wọn yoo fi eefin taba sinu eti naa, wọn si gbagbọ pe ara rẹ yoo da.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Camel sọ nigba kan wipe oun ni iru taba ti awọn dokita fẹran ju

Lẹyin ti wọn ri i pe taba ni oogun kan ti wọn n pe ni "nicotine" ni ọdun 1828, ni awọn onimọ ilera bẹrẹ si ni yẹra fun lilo taba diẹdiẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Lati bi ọgbọn ọdun bayii ni wọn ti ri i pe siga mimu ko dara run ilera.

Bayii, awọn siga igbalode (e-cigarettes) ti n rọpo taba. Ṣugbọn oun naa ni alebu tirẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Siga igbalode (e-cigarettes) ko ni ewu to taba

Ajọ WHO ni taba ti di ohun to jọ ajakalẹ arun ati pe o wa lara ohun to jẹ ewu fun alaafia ju lagbaye.

Ajọ naa tun ke si awọn orilẹ-ede lati fi ofin de lilo taba.

Ni ọdun 2016 ni wọn ni ida ogun ninu ọgọrun un eniyan lagbaye lo n mu taba bẹẹ wọn ida metadinlọgbọn ni lọdun 2010.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san