Mo ṣèèṣì gún ìyàwó mi pa ni -Deji Adenuga
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Ọrọ ìfẹ́ bí àdánwò ni ohun to ṣẹlẹ pẹlu Titi àti Deji ni Okiti pupa.

Eto tuntun ti BBC Yorùbá já lójú loni ni a pè ni: Ìròyìn Kàyééfì ti BBC Yorùbá.

Eto yii ni a o fi maa gbe àwọn iṣẹlẹ to gbẹnután, to ka ni láyà, to yanílẹnú wo káàkiri agbaye bẹrẹ lati Naijiria.

Lọsẹ yii, ìlú Igbódìgò ni Okiti Pupa nipinlẹ̀ Ondo ni BBC Yoruba ti ri Kayeefi yii o.

Nibẹ ni a ti ri Deji Adenuga ti awọn agbofinro n gbe lọ sile ẹjọ fún pe o dáná sun ọmọ meje ati iyawo rẹ ati ọkọ ẹgbọn iyawo rẹ mọle.

Jesu Oyingbo rèé, pásítọ̀ tó láṣẹ ìbálòpọ̀ lóri ọmọ ìjọ obìnrin

D.O Fagunwa kú, dúkìá rẹ̀ sì ń fọhùn síbẹ̀, ilé rẹ̀ rèé

Samuel Ladoke Akintọla jẹ́ Agbẹjọ́rò àti Akọ̀ròyìn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀

Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin

Àníyàn ìfẹ́ laarin Deji Williams Adenuga ati Titi Sanumi lo gba ẹ̀mí ọmọ Titi kan, ọmọ Jumọkẹ, to jẹ ẹgbọn Titi mẹfa ati ọkọ Jumọke.

Lẹyin ti Titi ko sinu ilé Deji tan lo gbọ pe Deji ti pa iyawo akọkọ rẹ nitori #450, 000 tẹlẹ.

Nigba ti BBC bi Deji leere o ni oun ṣeeṣi gún ìyàwó oun àkọ́kọ́ pa nítorí #450,000 ni.

Eyi lo mu Titi maa fẹ fi ọgbọn já Deji silẹ.

Ni Deji ba fọnmu pe oun ko gba. Ti ọrọ fi ba ẹyin yọ ti Deji lọ sun gbogbo ẹbi mọle.

BBC Yoruba ṣe iṣẹ iwadii iroyin yii de gongo ti a fi ba ọpọlọpọ ero to nii ṣe pẹlu iṣẹlẹ yii sọrọ.

Deji Adenuga funra rẹ, Iya Titi, Jumọkẹ, ẹgbọn Titi, Dokita to n tọju Titi, Oga ọlọpaa ti ẹjọ naa wa lọdọ rẹ, Oba ilu Igbodigo, Oba ilu Deji to ti sẹ̀ wá, àwọn ara ilu ati alafojuri ti ọrọ naa ṣoju wọn atawọn mii ni a ba sọrọ tan ki a le fidi okodoro ọrọ yii mulẹ.

A fi ki Olorun maa ṣo wa nibi ogun ni iṣẹlẹ yii jẹ.

Ọpọlọpọ lo n gba imọran pe asiko ti to ki a pada sidi awọn aṣa Yoruba to fini lọkan balẹ, bii ti iwadii ṣaaju igbeyawo ti ẹbi afẹsọna maa n ṣe.

Pataki igbesẹ iwadii ninu igbeyawo iran Yoruba ni ki obi ọkọ ati iyawo ṣe iwadii lẹyin ifojusode ati iṣẹ alarinna.

Iwadii yii lo maa fihan ẹbi iyawo awọn nkan to yẹ ki wọn mọ nipa ọdọmọkunrin to fẹ fẹ ọmọ wọn ati iru ẹbi to ti jade wa.