Ogun Assembly: Wọ́n ti ni kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Ogun lọ rọọ́kún nílé

Àkọlé àwòrán Irọ ló pa, a ti da awọn ti o yan sipo pada nitori ko tọna

Awọn ọmọ ilé igbimọ Aṣofin ipinlẹ Ogun ti wọgile gbogbo iyansipo ti Gomina Amosun ṣe ko to fipo silẹ.

Wọn ni awọn ṣe eyi lati fi yanju kudié-kudié ninu iyansipo naa ni ki ipinlẹ Ogun le tooro.

Ninu ijoko ilé ni wọn ti gbe ofin kan dide ti wọn fi ṣatunṣe yii.

Lẹyin ariwisi loriṣiiriṣii ni awọn ọmọ ilé fẹnuko pe awọn wọgile gbogbo ilana eto iṣuna tabi iṣẹ akanṣe ti Gomina Amosun ṣe tẹlẹ lai gba aṣẹ awọn ọmọ ile patapata.

Bakan naa ni wọn tun buwọlu ofin to tu gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ atawọn adari ajọ ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun gbogbo ti Amosun yan ká nitori wọn ti gba owo to tọ si wọn lọdọ ijọba to kogba wọle.

Awọn ọmọ ile igbimọ yii rọ gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ lati ko gbogbo ẹru ijọba to ba wa lọwọ koowa silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san

Wọn ni kawọn ọmọ ile pade lọjọ keje, oṣu kẹfa ọdun fun ijoko ilé tuntun.

Wọn tun ni iṣẹ iwadii yoo bẹrẹ lori awọn to ti ṣowo ilu mọkumọku.

Ni ipari, wọn fẹnuko pe ki gbogbo ori ade tuntun ti Amosun gbe ọpa aṣẹ le lọwọ ko to lọ pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ.

Agbẹnusọ ilé kede yiyansipo Ogbẹni Sonuga gẹgẹ bi olori ọmọ ile to pọju lọ lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMyanmar: kékeré ni wọ́n ti n kọ́ àwọn ọmọ nípa ọ̀nà oge ṣiṣe